NNEKA TA ỌMỌ Ẹ FUN OṢIṢẸ IJỌBA, LO BA FOWO Ẹ RA FOONU, BATA ATI AṢỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 10, 2019

NNEKA TA ỌMỌ Ẹ FUN OṢIṢẸ IJỌBA, LO BA FOWO Ẹ RA FOONU, BATA ATI AṢỌ

Ko sẹni to gbọ bi yaale ile kan, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37), Nneka Donatus ṣe sọrọ lọgba SARS laipẹ yi, lori bo ṣe ta ọmọ oojọ to ṣẹṣẹ bi, to si loun ti fowo naa ra foonu, aṣọ ati bata ti ko ni i gbe e ṣepe.

Bo tilẹ pe ọwọ ti tẹ Nneka atawọn to ta ọmọ naa fun lẹgbẹrun lọna ẹgbata (600,000), sibẹ oun tọpọ awọn to gbọ sọrọ naa n sọ ni pe ki wọn jẹ ki Nneka to ti bimọ marun tẹlẹ jiya ẹṣẹ ẹ, nitori pe ọdaju abiyamọ ni.

Si iyalẹnu, ọkan lara awọn oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Imo, Arabinrin Ujunwa Udechukwu, ẹni ogoji ọdun ati Nneoma Onwusereaka ni wọn ni Nneka ta ọmọ naa fun.

Nigba to n sọrọ, Nneka sọ pe oun ko dee de ta ọmọ naa, bi ko ṣe pe aile rowo tọju ẹ lo jẹ koun ta a, ati pe oun ti na ninu owo naa lati fi ra foonu, bata ati aṣọ, toun tun si fi ninu ẹ wọ mọto.

Ọdaju abiyamọ naa tun fi ye awọn ọlọpaa pe aṣiṣe ni oyun naa jẹ, nitori pe ọmọ marun loun ti bi tẹlẹ fun ọkọ oun tawọn ko jọ gbe papọ mọ, to si jẹ pe oun nikan loun n da bukata gbe, idi ni yii toun fi gbe igbesẹ naa.

A gbọ pe Nneka atawọ ọrẹ ẹ yoo foju bale ẹjọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI