TIRELA YAWỌ ỌGBA ILE ẸKỌỌ NILUU IBADAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 10, 2019

TIRELA YAWỌ ỌGBA ILE ẸKỌỌ NILUU IBADAN


Ori lo kọ awọn akẹkọọ ile ẹkọ kan ta a forukọ bo laṣiri, eyi to wa lagbegbe Ẹlẹyẹle niluu Ibadan laarọ oni, nitori pe asiko ti wọn n gbaradi lati jade lọọ ṣere ni tirẹla oniyẹpẹ kan yawọ ọgba ile ẹkọ naa.

AWIKONKO gbọ pe ijanu tirẹla naa lo ja lojiji lori ere ti wọn lo n ba bọ, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to wa leti. Opopona Ologunẹru lagbegbe Ẹlẹyẹle niṣẹlẹ naa ti waye.

Wọn ni dẹrẹba tirela naa ma ba a kọlu awọn eeyan lo mu ko yiwọ sẹgbẹ, to si lọọ kọlu fẹnsi ọgba ile ẹkọ naa.

Ohun tawọn eeyan n dupẹ lọwọ Ọlọrun fun ni pe ko ṣe ẹnikẹni leṣe, depodepo pe eeyan yoo ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI