NNKAN DE: KỌMIṢANA AMOSUN FIPO SILẸ LOJIJI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 15, 2019

NNKAN DE: KỌMIṢANA AMOSUN FIPO SILẸ LOJIJI

Iroyin tuntun to tun n lọ kaakiri igboro ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ bayii ni pe Kọmiṣana fọrọ oye jijẹ ati ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Babjide Ojuko ti kọwe fipo silẹ lojiji.

Bo tilẹ jẹ pe titi dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan la ko ti i gbọ nipa ẹkunrẹrẹ nnkan to ṣẹlẹ lori ipinu Baba naa lati kọwe fipo silẹ lasiko ti ijọba Gomina Amosun ṣe ku ọjọ meloo kan ko pari bayii, ṣugbọn ohun ta a gbọ ni pe ko fu ẹnikẹnikẹni lara ko too kọwe naa sita.

Amugbalẹgbẹ lori ọrọ iroyin, Arabinrin Oluwaṣeun Boye fidi ẹ mulẹ f'AWIKONKO laipẹ yi, bo tilẹ jẹ pe obinrin naa kọ lati sọ idi pataki ti ọga ẹ fi gbe igbesẹ naa.

Ẹkurẹrẹ iroyin naa n bọ laipẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI