AWỌN AWUSA FI TIRELA DANGOTE DA WAHALA SILẸ L’ABẸOKUTA, ỌPỌLỌPỌ DUKIA LO ṢOFO DANU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 13, 2019

AWỌN AWUSA FI TIRELA DANGOTE DA WAHALA SILẸ L’ABẸOKUTA, ỌPỌLỌPỌ DUKIA LO ṢOFO DANU

...Lawọn araalu ba n fẹsun kan Ijọba ipinlẹ Ogun

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta: Ko sẹni to de ile nla gogoro kan to rẹwa daadaa ladugbo Agọ-Oko nitosi Ṣapọn niluu Abẹokuta laarọ oni, ti ko ni i bu sẹkun pẹlu bi tirela Dangote ṣe kọlu ṣọọbu, to si fi ọpọlọpọ dukia ṣofo danu.

Bo tilẹ jẹ pe a ko ti i le fidi nnkan to fa ijamba nla to ku diẹ ko gba ẹmi awọn eeyan dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan, ṣugbọn sibẹ, bawọn kan ṣe n sọ pe ṣe lawọn to wa tirela naa gbagbe sun lori ere, tawọn min in sọ pe ijanu tirela naa lo deede ja sọnu, bẹẹ lawọn min n tun n fẹsun kan ijọba ipinlẹ Ogun pe iṣẹ ọwọ wọn lo n dahun.

AWIKONKO gbọ, ni nnkan bi aago mejila oru onii, Mọnde ni wọn sọ pe ijamba naa ṣẹlẹ, ti wọn si lawọn awusa mẹta ni wọn wa ninu ẹ lasiko naa. Okuta nla-nla ni wọn ni wọn fi tirela naa n ko lọ, ati pe agbegbe Ake ni wọn ti n bọ.

Bi wọn ṣe de agbegbe Agọ-Oko lati yi soju ọna to lọ si Ṣapọn ni wọn sọ pe tirela naa sọda sodikeji, to si lọọ kọlu ṣọọbu nla kan ti wọn ṣẹṣẹ kọ, ti wọn ti n ta oriṣiriṣi ọti ẹlẹrindodo, gbogbo ọja ti wọn loo wa ninu ṣọọbu naa lo bajẹ kọja afẹnusọ.

A gbọ pe bijamba naa ṣe ṣẹlẹ ni wọn sọ pe meji ninu awọn awusa ti wọn wa tirela naa ti gba tẹṣan ọlọpaa Oke-Itoku to wa nitosi ibi iṣẹlẹ naa lọ lati lọọ fi to wọn leti, nigba tawọn yẹn si ri nnkan to ṣẹlẹ ni wọn ti ranṣẹ sawọn to ni ṣọọbu naa ni nnkan bi aago meji oru.

Bawọn awusa naa ṣe n ṣe, to dabi pe wọn fẹẹ daku lo mu kawọn ọlọpaa naa ni ki wọn lọọ tọju ara wọn lọsibitu, ki wọn si pada wa lati wa a tẹsiwaju ẹjọ naa, gẹgẹ bi wọn ṣe fi to wa leti.

Lara awọn araadugbo naa ti wọn b’AWIKONKO sọrọ nibi iṣẹlẹ naa ni wọn sọ pe ko jẹ tuntun nitori pe iru nnkan bẹẹ ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ, tawọn si ti fọrọ naa to ijọba ipinlẹ Ogun leti, ṣugbọn ti wọn ko dahun.

Wọn ni ko sigba tiru ijamba bẹẹ ba ṣẹlẹ, ogunlọgọ dukia lo maa n ba a lọ, tijọba ko si ni i gbe igbesẹ lati wa iyanju si nnkan to n fa ijamba naa, bo tilẹ jẹ pe eyi to ṣẹlẹ yi ko la ẹmi eeyan kankan lọ.

Nigba to n fi omije sọrọ, Ọgbẹni Matthew to ni ṣọọbu naa sọ pe ni nnkan bi aago meji oru ni wọn pe oun pe tirela kọlu ṣọọbu, ibanujẹ ọkan lo si jẹ foun nigba toun dbẹ, toun ri bi ọja toun ṣẹṣẹ ja lopin ọsẹ to kọja yi ṣe bajẹ.

“Ọti ẹlẹrindodo onike ni mo n ta, alagbata ni mi. Nnkan bi aago mejila ni wọn loo ṣẹlẹ, ṣugbọn bii aago meji ku diẹ ko lu ni mo de ibi yi lati wa a wo o. Ko sẹni to ku nibẹ, ṣugbọn wọn jẹ ko ye mi pe awọn to wa a farapa. Bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ ni wọn sọ pe wọn gba tẹṣan ọlọpaa lọ lati lọọ fi to wọn leti.

“Latibẹẹ ni wọn ti sọ pe ki wọn lọọ tọju ara wọn ni ọsibitu. Meji ni wọn sọ pe awọn awusa ti wọn lọ tẹṣan. ọjọ Sande ana ni wọn ṣẹṣẹ wa a ba mi ja ọja yi, diẹ lowo ọja yi si fi le ni miliọnu meji naira, yatọ sawọn ọja ti wọn ti wa ninu ṣọọbu tẹlẹ.

“Nnkan ti mo fẹ kileeṣẹ Dangote mọ ni pe, wọn gbọdọ wa a da si nnkan to bajẹ yi, mo si fẹ kijọba ipinlẹ Ogun wa a ṣe nnkan si oju ọna yi tori pe iru nnkan bayii ko ṣẹṣẹ maa ṣẹlẹ. O yẹ kijọba ba wa ṣe bọọbu to n da mọto duro diẹ kọja soju ọna yi, lati le din ijamba bayii ku, ai si bọmbu yi lo n fa ọpọlọpọ ijamba nibi.”

Ṣaaju asiko yi ni Arabinrin Adebẹṣin ti ṣọọbu wa nitosi ninu ọrọ ti ẹ sọ pe “A dupẹ pe oru nijamba yi ṣẹlẹ, to ba jẹ pe ọsan gangan ni, o ṣeeṣs ko ju bayii lọ, tori pe ibi tawọn ọmọde ti maa n ṣere ni nibi tijamba naa ti waye yi.

“Nnkan ti mo fẹẹ sọ ni pe, mo fẹẹ rawọ ẹbẹ sijọba wa, pe iru nnkan bayii ko ṣẹṣẹ ma a ṣẹlẹ loju ọna Ag-o-Oko yi, ki wọn wa ba wa ṣe bọmbu sibi, tori pe ijamba naa ti n pọ ju. Ọja to wa ninu ṣọọbu yẹn ko din ni miliọnu, ṣugbọn ẹni to ni i lo le sọ pato iye miliọnu to jẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI