ỌRỌ BURUKU TOUN TẸRIN: TITI ṢẸ OYUN DEJI, NI DEJI BA LỌỌ DANA SUN MỌLẸBI TITI MẸSAN L'ONDO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 24, 2019

ỌRỌ BURUKU TOUN TẸRIN: TITI ṢẸ OYUN DEJI, NI DEJI BA LỌỌ DANA SUN MỌLẸBI TITI MẸSAN L'ONDO

Ọrọ buruku tẹrin nigba ti baale ile ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Deji Adenuga n sọrọ lọgba olu-ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo laipẹ yi, to si ṣalaye idi to fi dana sun mọlẹbi afẹsọna ẹ mẹsan an mọle.

Gẹgẹ AWIKONKO ṣe gbọ, wọn ni ọdun to kọja ni Deji pade afẹsọna ẹ, Titi Ṣanumi, ti wọn si ba ara wọn sọrọ ifẹ, ko pẹ la gbọ pe Titi ko de ile Deji, ti wọn si bẹrẹ sii gbe bii tọkọ-taya.

Ojoojumọ ni wọn sọ pe wahala maa n ṣẹlẹ laarin awọn mejeeji, ti wọn si ni ẹgbọn Titi kan ti wọn pe oruko ẹ ni Jumọkẹ lo n da wahala naa silẹ.

A ti ẹ tun gbọ pe ọpọ igba lawọn eeyan naa ti ko ara wọn lọ si tẹṣan ọlọpaa, tawọn ọlọpaa si sọ pe ki wọn lọọ fi eegun otolo too ọrọ wọn, tori pe iwọnba ni ileeṣẹ ọlọpaa le da si ọrọ ọkọ ati'yawo mọ.

Teṣan ọlọpaa ti wọn lọ gbẹyin lọjọ Tusde ijẹrin to kọja yi la gbọ pe inu ti bi Deji, to si pada sile pẹlu ibanujẹ, wọn nibi to jokoo si to ti n ronu lero buruku kan ti sọ sii lọkan pe koun dana sun Titi ati Jumọkẹ mọle.

Eyi gan an ni wọn loo muu ko gbe kẹẹgi, to si gba ile epo lọ lati ra bẹntiroolu, to si gba ile awọn mọlẹbi Titi lọ lalẹ ọjọ naa. Wọn ni bo ṣe debẹ lo da bẹntiroolu naa silẹ, to si ṣa ina sii, ko too salọ.

Awọn to ri Deji lasiko naa ni wọn lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, tọwọ si tẹẹ lọjọ kẹta, ti i ṣe ana.

Nigba to n sọrọ, Deji sọ pe oun ko mọn ọn mọ dana sun awọn mẹsan an mọle, ati pe Titi ati Jumọkẹ nikan loun ni lero lati dana sun tori pe awọn naa ti leri iku soun tẹlẹ.

Ninu ọrọ rẹ lo tun tijẹ ko di mimọ pe oyun oṣu mẹrin oun to wa ninu Titi, eyi to fibinu ṣẹ danu lo tun fa igbesẹ naa, tori pe iwa ọdaju lo hu naa. Bẹẹ lo tun sọ pe oun ṣakiyesi pe Titi ati Jumọkẹ kan n gba owo lọwọ oun lasan ni, kii ṣe pe Titi nifẹ oun denu.

Bo tilẹ jẹ pe Deji sọ pe oun kabamọ fun iwa buruku naa, ati pe oun ko ronu pe boya aṣiri oun le pada tuu, sibẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo labẹ Kọmiṣana wọn, Undie Adie ti sọ pe Deji yoo foju bale ẹjọ laipẹ.

Pupọ ninu awọn to gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn n fi epe rabandẹ-rabandẹ raṣẹ si Deji fun igbesẹ naa titi dasiko ti a kọ iroyin yi tan. bẹẹ ni Titi naa wa lẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun nibi to ti n gba itọju lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI