O MA ṢE O: AKẸKỌỌ FASITI GAN MỌ INA L’ỌṢUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 24, 2019

O MA ṢE O: AKẸKỌỌ FASITI GAN MỌ INA L’ỌṢUN

Inu ibanujẹ ọkan lawọn mọlẹbi ọdọmọkunrin akẹkọọ ile ẹkọ fasiti Oduduwa to wa nipinlẹ Ọṣun wa dasiko ti a kọ iroyin yi tan, latari bo ṣe gan mọ ina lọjọ Wẹside ijẹta.

Aṣhante lorukọ akẹkọọ naa, ti wọn si nipele keji (200L) lo wa ko too kagbako iku naa ni Ipetumọdu.

AWIKONKO gbọ pe fooni ni wọn Aṣhante n gba ina si lọwọ lalẹ ọjọ Wẹside naa, paapaa ti wọn tun sọ pe asiko ti ojo n rọ lọwọ ni.

Wọn ẹrọ to n gba ina sara (transformer) la gbọ pe o gba ina lojiji, to si jẹ pe asiko naa ni Ashante fi waya sinu ina, lojiji ni wọn sọ pe ina gbe oun naa.

Awọn ọlọpaa la gbọ pe wọn pada wa gbe oku e kuro lọjọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI