WỌN DANA SUN ỌDỌMỌKUNRIN MEJI NITORI ẸSUN IDIGUNJALE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 3, 2019

WỌN DANA SUN ỌDỌMỌKUNRIN MEJI NITORI ẸSUN IDIGUNJALE

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, to ba jẹ pe wọn n ra koro de ajule-ọrun ni, o ṣee ṣe kawọn ọdọmọkunrin meji ti wọn lu pa lọjọ Wẹside to kọja yi ti ba Ọlọrun lalejo latari ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

Ijọba ibilẹ Ikeduru nipinlẹ Imo la gbọ pe aṣiri awọn ọdọmọkunrin meji naa ti tu, ta a si gbọ pe awọn gan an ni wọn n lọwọ bi dukia ṣe n sọnu lagbegbe naa, ti wọn si n pawọn araalu lẹkun jaye.

 
Bo tilẹ jẹ pe AWIKONKO ko ti i gbọ nipa kulẹ-kulẹ biṣẹlẹ naa ṣe waye, ṣugbọn ta a gbọ pe nigba taṣiri wọn maa tu, pẹlu ọkada ti wọn ni wọn ṣẹṣẹ ji gbe ni wọn ka mọ wọn lọwọ.

Bọwọ ṣe tẹ awọn meji naa la gbọ pe wọn kọkọ foju wọn han kaakiri igboro, ko to odi pe wọn ko taya moto si wọn lọrun, ti wọn si lu wọn pa, ko da a, ta a gbọ pe wọn dana sun wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI