WỌN LE ARSENAL ATI MAN U LỌ EUROPA LEAGUE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 5, 2019

WỌN LE ARSENAL ATI MAN U LỌ EUROPA LEAGUE

Aṣe tẹni to de laari, a ko mọ tẹni to n bọ. Ẹgbẹ agbabọọlu Arsenal naa ti tẹle Manchester United lọ si idije Europa.

Arsenal naa ta ọmi ayo kọọkan pẹlu ikọ agbabọọlu Brighton ni papa iṣere Emirates, eleyi to tumọ si pe wọn ko le de ipo kẹrin mọ lori tabili idije Premier League fun saa yii.

Ẹlẹsẹ ayo Pierre-Emerick Aubameyang lo kọkọ gba pẹnariti sawọn fun Arsenal lẹyin iṣẹju mẹsan an ti ere bọọlu naa bẹrẹ.

Ṣugbọn Glenn Murray dayo ọhun pada lẹyin to yẹ ile Arsenal pẹlu pẹnariti ti wọn fun ẹgbẹ agbabọọlu Brighton.

Ẹwẹ, ẹgbẹ agbabọọlu Manchester United ti dero Europa League bayii lẹyin ti wọn ta ọmi alayo kọọkan pẹlu Huddersfield Town.

Esi ifẹsẹwọnsẹ yii ti ṣakoba fun ikọ Man U lati kopa ninu idije Champions League ni saa to n bọ.

Scott McTominay lo kọkọ gba goolu sawọn fun Manchester United lẹyin iṣẹju mẹjọ ti wọn bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa.

Ṣugbọn Isaac Mbenza dayo naa pada lẹyin iṣẹju mẹẹdogun ti abala keji ere bọọlu ọhun bẹrẹ.

Ẹgbẹ agbabọọlu Man U kuna bayii lati yege fun idije Champions League ni saa ere bọọlu to n bọ.

Chelsea ati Tottenham ti wẹ tan kan-in kan-in bayii lati ṣoju ilẹ Gẹẹsi ninu idije Champions League ni saa to n bọ.

- BBC

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI