ỌWỌ TẸ GILBERT TO N FAṢỌ ṢỌJA LU JIBITI L'OGIJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 5, 2019

ỌWỌ TẸ GILBERT TO N FAṢỌ ṢỌJA LU JIBITI L'OGIJO

Ko tii daju pe ọdọmọkunrin ẹni ọdun mejila kan, Jolly Gilbert yoo bọ ninu wahala to tọrun ara rẹ bọ yi, latari bi wọn lo ṣe n fi aṣọ ologun, iyẹn ṣọja lu awọn araalu ni jibiti owo ati dukia wọn.

Oni, ti i ṣe Sande, ọjọ karun-un oṣu karun la gbọ pe ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ lagbegbe Eyin-Ogbe niluu Ogijo, ipinlẹ Ogun, iyẹn lahamọ awọn ọdaran wọn. AWIKONKO gbọ pe ki i ṣe Gilbert nikan lọwọ tẹ, a gbọ pe pẹlu awọn meji kan lakara wọn jọ tu sepo.

Lasiko tọwọ tẹ Gilbert pẹlu awọn ẹmẹwa ẹ, ohun to n sọ ni pe ṣọja loun, ati pe 174 Battalion loun n ba ṣiṣṣe, idi ni yii, ti wọn lawọn ọlọpaa naa fi kan si ọfiisi wọn, tawọn yẹn si sọ pe awọn ko mọ ọn ri rara.

Baṣiri yi ṣe tu sawọn ọlọpaa lo ti mu ohun ẹbẹ pe ki wọn ṣe oun jẹjẹ, tawọn yẹn si ni ile ẹjọ ni yoo paṣẹ boya wọn yoo tu silẹ, tabi yoo ṣẹwọn, kii ṣe awọn.

Lara awọn nnkan ti wọn gba lọwọ ẹ ni Kaadi idanimọ iṣẹ ṣọja, ọbẹ, aṣọ ṣọja, oogun abẹnugọngọ, atawọn irinṣẹ ologun loriṣiriṣi.

Ni bayii, Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Bashir Makama ti paṣẹ pe ko ṣo lọọ gbatẹgun igbalode diẹ lọgba SARS digba ti yoo fi fọju bale ẹjọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI