AAYE ṢI SILẸ FAWỌN ILE-IṢẸ NLA-NLA LATI WỌ IPINLẸ WA - SALAKỌ-OYEDELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 28, 2019

AAYE ṢI SILẸ FAWỌN ILE-IṢẸ NLA-NLA LATI WỌ IPINLẸ WA - SALAKỌ-OYEDELE

Oluwaṣeun Boye

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti jẹ ko di mimọ pe ijọba ipinlẹ naa ti ṣi aaye silẹ fun gbogbo awọn olokoowo to ba fẹẹ wa a da ile-iṣẹ yala, nla ni tabi kereje silẹ fun idasoke ọrọ aje.

Onimọ-ẹrọ, Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa laipẹ yii lasiko to n bawọn alaṣẹ ile-iṣẹ Banki kan, Gateway Mortgage Ban, eyi ti Ọgbẹni Ọlawale Ọṣisanya to jẹ olori wọn lewaju fun.
 
Nibẹ lo ti jẹ ko ye wọn pe ijọba Dapọ Abiọdun ti mura silẹ lati bẹrẹ awọn igbesẹ ti yoo mu kawọn olokoowo rẹpẹtẹ wọ ipinlẹ naa wa, ki eto ọrọ aje le tubọ gun oke sii.

O ni eto ọrọ aje tijọba n gbe igbesẹ pe ko le gun oke, kii ṣe fun anfaani ijọba, bi ko ṣe fun anfaani awọn araalu, paapaa awọn olokoowo kekeeke.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI