ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ ÀJỌ EFCC DÁ ÌWÉ ÌRÌNNÀ DOYIN ÒKÚPÈ PADÀ FUN NÍ KÍÁKÍÁ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, June 28, 2019

ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ ÀJỌ EFCC DÁ ÌWÉ ÌRÌNNÀ DOYIN ÒKÚPÈ PADÀ FUN NÍ KÍÁKÍÁ


Bẹ ó bá gbàgbé, láìpẹ́ yí la mú ìròyìn náà wá fún un yín pé àfàìmọ̀ kí ilé ẹjọ́ má padà dá Dọ́kítọ̀ Doyin Òkúpè lára látàrí ẹ̀sùn tí àjọ EFCC fi kan án pé ó ṣe owó ìlú kúmọkúmọ. 

A sì jẹ kò yẹ ẹ yín pé ọjọ́ Ẹtì òní ni ìgbẹ́jọ́ min in yóò wáyé. 

Ní báyìí, ilé ẹjọ́ gíga tó fíkàlẹ̀ siluu Àbújá tí pàṣẹ pé kí àjọ náà dá ìwé irinna Okupe tó jẹ́ agbẹnusọ fún Ààrẹ àná, Dọ́kítọ̀ Goodluck Ebele Jonathan padà, pé ẹ̀sùn tí wọn fi kan án kò ní nǹkan án ṣe peluu irinna ẹ sókè òkun. 

Bo tilẹ̀ jẹ́ pé ìgbẹ́jọ́ náà kò tíì parí, ṣùgbọ́n síbẹ̀, wọn tí sún ìdájọ́ sì ọjọ́ kẹta oṣù kẹwàá ọdún yìí. 

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI