AGUNBANIRO TO POKUNSO L'ỌYỌ, WỌN NI KII ṢOJU LASAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 17, 2019

AGUNBANIRO TO POKUNSO L'ỌYỌ, WỌN NI KII ṢOJU LASAN

Lọjọ Fraide ọsẹ to kọja yi ni iroyin naa tan kaakiri orilẹ-ede Naijiria, paapaa lagbaye pe ọdọmọkunrin agunbanirọ kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Johnson Onyilo deede pokunso, to si gbagbẹ sọda sọrun alakeji.

Iroyin naa ṣe ọpọ awọn to gbọ ni kaayefi, ko da a, tawọn ti wọn jọ n gbe inu atawọn ọrẹ rẹ gan an ṣi wa ninu ironu, ti wọn si n ṣe iwadii lori bo ṣe pinu lati gba ẹmi ara rẹ.

Ipele keji (Batch B, Stream 1) la gbọ pe Johnson, ọmọ bibi ilu Makurdi nipinlẹ Benue naa wa, ta a si gbọ pe ẹka ikẹkọọ iṣiro (Accounting) lo ti kẹkọọ jade ni fasiti ipinlẹ Jos to wa niluu Plateau.

Bawọn kan ṣe n sọ pe iku Johnson lọwọ aye ninu, bẹẹ lawọn kan n sọ pe kii ṣoju lasan, tawọn min in si n sọ pe, ko ma jẹ pe ọrẹbinrin rẹ lo ja a ju silẹ lojiji.

Ohun ta a gbọ daju ni pe, iwadii ti bẹrẹ lori idi ti Johnson fi gba ẹmi ara rẹ. 

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI