KAYEEFI NLA: IYAALE ILE FI OYUN ỌDUN MẸTA BI ẸWURẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 17, 2019

KAYEEFI NLA: IYAALE ILE FI OYUN ỌDUN MẸTA BI ẸWURẸ

Gbenga Ọladipupọ

Gbogbo awọn ara agbegbe kan ti wọn pe ni Karaka to wa ni Rumuowha niluu Port Harcourt, iyẹn nipinlẹ Rivers ni wọn ko le tete gbagbe ọjọ Sande ana latari iṣẹlẹ kayeefi nla to mi gbogbo ilu titi.

Ohun ta a gbọ ni pe iyaale ile kan to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Abia, ṣugbọn to jẹ pe iluu Port Harcourt loun ati ọkọ ẹ, toun jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Akwa Ibọm fi ṣe ibugbe.

AWIKONKO gbọ pe ọdun mẹta sẹyin ni iyaale ile naa ti a ko tii mọ orukọ ẹ di asiko ti a kọ iroyin yi tan ti finu ṣoyun, ti wọn si n reti ọjọ ikunlẹ lẹyin oṣu mẹsan an, ṣugbọn ti oyun naa pada ọdun mẹta mọ ọn ninu.

Bi wọn ṣe n ti ori-oke kan bọ sibo min in naa ni wọn ko gbẹyin nile awọn alaafaa, bakan naa la gbọ pe wọn ti ṣetutu loriṣiriṣi, ko da a, ta a tun gbọ pe gbogbo nnkan ni wọn ti ṣe lati le jẹ ki ọmọ naa waye.

Ṣugbọn lọjọ Sande ana la gbọ pe ṣadede ni wọn ni ọmọ bẹrẹ sii mu obinrin yi lẹyin asejẹ kan ti wọn loo jẹ, tawọn eeyan, paapaa awọn to sunmọ ọn si bẹrẹ sii dunnu pe ọdun iṣoro ẹ dopin, ati pe ọmọ lanti-lanti ni yoo bi.

A gbọ pe nibi ti wọn ti n mu obinrin naa lọ si inu yara ti yoo bimọ si, lo to ti ṣubu lulẹ, nigba ti kinni si maa jade loju ara rẹ, iyalẹnu lo jẹ fawọn to wa nibẹ pe ewurẹ lo jade labẹ ẹ.

Loju ẹsẹ la gbọ pe awọn ero ti pe si ile naa, nigba tawọn tọrọ naa ṣoju wọn ti pariwo sita pe kawọn araalu wa a wo nnkan abami toju wọn ri lọjọ Sande.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI