AJỌ EFCC RI OBITIBITI OWO HE, NILE ẸJỌ BA PAṢẸ KI WỌN MAA GBE E LỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 29, 2019

AJỌ EFCC RI OBITIBITI OWO HE, NILE ẸJỌ BA PAṢẸ KI WỌN MAA GBE E LỌ

Ile ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Kaduna lọjọ Ẹti to kọja yi ti paṣẹ pe ki ajọ EFCC ma a gbe obitbiti owo ti wọn ri gba ni papakọ ofurufu to wa niluu Kaduna lọjọ kẹrinla oṣu kẹta ọdun yi lọ, ati pe ki wọn lọọ da owo naa sinu apo owo ijọba apapọ orilẹ-ede yi.

 
Onidajọ S. M. Shuaibu lo gbe idajọ naa kalẹ pe wọn ko gbọdọ da owo naa ti ko din ni miliọnu mọkandinlaadọta (N49,000,000) naira pada sibi ti wọn ti gba a, tabi gbe e fẹnikẹni.

 
Owo naa la gbọ pe aganran ni gbogbo ẹ jẹ, ati pe baagi ọra nla marun ọtọọtọ ni wọn ko owo naa sii, ta a si gbọ pe wọn fẹẹ gbe owo naa wọ ọkọ ofurufu ki aṣiri too tu ni.

 
Ajọ EFCC naa la gbọ pe wọn bẹbẹ pe ki wọn jẹ kawọn maa gbe owo naa lọ tori pe ẹri fidi ẹ mulẹ pe owo i wọn lọọ jigbe kuro lapo ijọba apapọ orilẹ-ede yi ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI