ỌMU MI MEJEEJI NI MO FI N GBA NNKAN TI MO BA FẸ LỌWỌ AWỌN EEYAN - GBAJUMỌ OṢERE TIATA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Saturday, June 29, 2019

ỌMU MI MEJEEJI NI MO FI N GBA NNKAN TI MO BA FẸ LỌWỌ AWỌN EEYAN - GBAJUMỌ OṢERE TIATA

Ọrọ buruku toun tẹrin nigba ti ọkan lara awọn agbajugba oṣere tiata nni, Cherry Entafield sọ pe ọmu oun mejeeji loun fi n gba nnkan toun ba fẹ lọwọ awọn eeyan, nitori pe ọpọ igba loun ti gbiyanju lati gba nnkan toun ba fẹ, ṣugbọn toun kii ri gba, idi ni yii toun ṣe n lo awọn ẹbun ti Ọlọrun foun lati fi gba nnkan lọwọ awọn eeyan.

Oni Abamẹta ni ilu mọn ọn kan oṣere tiata to tun n jo ajota (dancer) naa sọrọ fun ọkan lara awọn oniroyin, to si ni ko si nnkan toun fẹ nile aye yi, ti ọmu oun kii gba foun lọwọ awọn toun ba fẹẹ gba nnkan lọwọ wọn.

Cherry sọ pe loootọ loun ni ẹbun, ṣugbọn oun ti gbiyanju lati jẹ kawọn eeyan mọ iru ẹbun toun ni, ṣugbọn ti ko sẹni to wo ibi toun wa rara, idi ni yii toun tun fi jokoo lati ronu ọna toun fi yoo fi maa ri owo jẹun, toun si ronu kan ẹbun ọmu mejeeji ti Ọlọrun foun lati maa fi gba nnkan lọwọ awọn eeyan, toun si bẹrẹ iṣẹ ajota.

 
Ninu ọrọ rẹ lo ti sọ pe oriṣiriṣi ẹbun ni Ọlọrun fi ta oun lọrẹ, toun si ti lo lati jẹ kawọn eeyan mọ iru eeyan toun jẹ, ṣugbọn to jẹ pe ọpọ awọn eeyan ni ko kọbi ara sii, toun tun n kọ oriṣiriṣi ewi jade sita fawọn eeyan, tẹnikẹni ko si wo ibẹ.

O sọ pe ṣugbọn ni bayii toun ti di gbajumọ, ọpọ awọn ewi toun ti gbe sita tẹlẹ, toun tun ṣẹṣẹ n gbe jade diẹdiẹ bayii lawọn eeyan tun ri gẹgẹ bi ẹbun tuntun ti Ọlọrun foun laimọ pe o ti pẹ toun ti n gbe wọn jade.

Bakan na lo wa a jẹ kawọn eeyan mọ pe lati ile iwe alakọbẹrẹ loun ti fẹran ijo jijo, to si jẹ pe oun ni olori ẹgbẹ awọn to n jo ta nile iwe girama, ati pe iṣẹ toun ko tii le sọ boya oun yoo fi silẹ ni iṣẹ alajota, nitori pe nnkan to n di owo lasiko yi foun niyẹn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI