Bi ẹ ṣe n kọ iroyin yi lọwọlọwọ, ara ko rokun, bẹẹ ni ara ko ro adiyẹ nipinlẹ Ọyọ laarin awọn ọlọpaa atawọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ti NURTW, nigba ti wọn lawọn ọmọ ẹgbẹ onimọto naa ko awọn nnkan ija oloro kaakiri ipinlẹ naa lati lọọ gba garaji ni tipatipa.
AWIKONKO gbọ pe lọjọ Wẹside to kọja yi ni wọn lawọn janduku gba ọfiisi alaga ẹgbẹ naa lọ, iyẹn Abideen Ejiogbe lagbegbe Orita-Challenge ti wọn si lọọ lu awọn to wa nibẹ lero lati gba ijọba mọn ọn lọwọ.
Wọn ni biroyin yi ṣe tẹ awọn ọlọpaa lọwọ ni wọn ti bẹrẹ igbesẹ lati rọwọ to awọn eeyan, paapaa nigba ti wọn tun sọ pe awọn eeyan naa tun ko awọn nnkan ija oloro lọ sibi ti wọn ti bura fun Gomina tuntun, Ṣeyi Makinde, tọwọ si tẹ ninu wọn.
Eyi gan an la gbọ pe o fa a ki Gomina tuntun
niinlẹ Ọyọ, Onimọ-ẹrọ Ṣeyi Makinde paṣẹ pe oun ko fẹẹ ri awọn ọmọ ẹgbẹ
onimọto to n jẹ NURTW kankan mọ nipinlẹ naa, ati pe ijọba ti gbakoso
gbogbo garaaji patapata.
Kọmiṣana ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Shina Olukolu fidi ẹ mulẹ pe ko din ni mọkandinlọgbọn lawọn ọmọ ẹgbẹ naa tọwọ ti tẹ latari wahala ti wọn n da silẹ niluu, tawọn ko si ni i laju silẹ kiluu naa bajẹ mọ wọn lori.
No comments:
Post a Comment