ẸGBẸRUN MARUN AWỌN EEYAN WA TI WA NITA - ỌGA FIJILANTE NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 4, 2019

ẸGBẸRUN MARUN AWỌN EEYAN WA TI WA NITA - ỌGA FIJILANTE NIPINLẸ OGUN

Bi a ba n so nipa ileese eleto aabo to sunmo awon araalu daadaa, odu lawon Fijilante, paapaa awon VGN tijoba apapo, won kii sai mo foloko, opo awon araalu ni won si ti n kan saara si won ni gbogbo igba pelu awon akanse ise lati daabo bo emi ati dukia awon araalu.

Bawon ileese nla-nla ati kereje-kereje se n gbosuba kare fun won, bee lawon iyaloja, awon agbaagbe lawon agbegbe kaakiri naa n gbe osuba kare fun won, paapaa bi won tun se n fowosowopo pelu won nipa idanilekoo ati oniruuru eto to nii se pelu oro eto aabo.

Lonii tii se ayeye odun itunu aawe fawọn Musulumi kaakiri agbaye ni adari egbe Fijilante, VGN, Komanda Nureni Olanrewaju Adedoyin sọ pe gbogbo eto lo ti n lo ni sepe nipa eto ti won ni fawon araalu, bi asiko odun itunu aawe se n lo lowo.

Olanrewaju so pe oniruuru eto olokan-o-jokan nileese won ti la kale lati rii pe aabo emi ati dukia awon araalu daju, nitori e lo so pe awon se da àwọn ọmọ ẹgbẹ àwọn ti ko din ni egberun marun sita lasiko odun yi.

O ni biru asiko odun bayii ba ti n wa nita lawon onise ibi maa n kaakiri lati wa nnkan ti won maa ji gbe, ati bi won se maa femi eeyan sofo, ti won a tun pinu lati feeyan sofo nitori owo ojiji ti won n wa.

Komanda Olanrewaju ni ileese won, paapaa nipinle Ogun, awon ti gbe ise le gbogbo awon osise won lowo lati rii pe ko seni to huwa odaran laarin ilu atawon igberiko kaakiri ipinle. Bee lo to pe titi de awon ile ifowopamo atawon ibi ti won ti n gbowo pajawiri, ATM ni ki won maa sabojuto.

Ninu oro e, Olanrewaju so pe “A ni eto ati ilana ti wa ta a gbe kale fun ayeye odun itunnu aawe yi. A ti ran awon osise wa patapata lati loo daabo bo awon eeyan ilu. A tun ti ran won loo darapo mo awon olopaa, FIB, ileese otelemuye, ajo eso oju popona atawon to n ri soro egboogi oloro, ati beebeelo. Won gbodo rii pe won fo ilu mo tonitoni.

“Nigba ti ilu ba wa nimototo, a maa rii pe ko ni siwa odaran, eeyan ko ni ronu lati huwa odaran, alaafia a si wa. Kaakiri awon igberiko, agbegbe la ti yan awon osise wa lati loo sise aabo. Ko si iberu fawon araalu nitori pe digbi ni eto aabo ta a ti se sile.”

Nigba to n soro nipa ipo ti eto aabo wa nipinle Ogun, Komanda naa so pe ipo to dara ni eto aabo wa, sugbon nnkan to kan fe e je ko maa mehe diedie ni toro oselu to wa nita bayii, sugbon gbogbo e lo wa labe ikawo wa.

Nipa ti aseyori won laarin osu mejila seyin, o ni orisirisi aseyori tawon ko le ka tan nileese won ti se, tawon araalu, atawon ileese eleto aabo si ti gbe osuba kare fun won.

Bo tile je pe ko sise to yanranti ti ni adojuko, nigba to n soro lori adojuko ileese won, Komanda Olanrewaju so pe opo adojuko lawon ni, sugbon eyi to lewaju gbogbo e ni ti isoro aisi irinse ati irinse, paapaa isoro owo ti ko to lo n fa tileese won fi n padanu awon ise kookan.

Fun idi eyi, oga agba naa ro ijoba apapo, ijoba ipinle ati ijoba ibile, to fi mo awon ileese adani lati dide iranlowo si won, ki ise won si le tubo yanranti daadaa.

Ni ti eto idibo to n bo lona ati ipolongo idibo to n lo lowo, Adedoyin ni awon ko si fun enikeni bi ko se gbogbo eeyan, ati pe awon ko si leyin oloselu kankan bi ko se pee ni to ba kowe iranlowo nipa eto aabo lawon yoo dide iranlowo si.

Lakotan, oga agba naa wa gbawon araalu atawon oloselu lamonran pe ki won yago fun nnkan to le mu ki won sewon lasiko ati leyin odun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI