BI Ẹ FẸ, BI Ẹ KỌ, IṢẸ AGBẸ LA MAA FI TUN IPINLẸ ỌYỌ ṢE - GOMINA MAKINDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 16, 2019

BI Ẹ FẸ, BI Ẹ KỌ, IṢẸ AGBẸ LA MAA FI TUN IPINLẸ ỌYỌ ṢE - GOMINA MAKINDE

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Ṣeyi Makinde ti sọ ọ di mimọ fun gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ naa pe ko si ọna min in tijọba ni lọkan lati fi mu idagbasoke ba ipinlẹ naa, bi ko ṣe nipa iṣẹ agbẹ, paapaa ọgbin in.

O sọrọ naa niluu Eruwa nibi ayẹyẹ kan ti wọn pe e si gẹgẹ bi alejo pataki, o ni fun ọdun mẹrin ijọba oun, iṣẹ agbẹ lawọn yoo gbe dide lati fi imu ayipada rere de ipinlẹ naa, ti yoo si mu gbogbo ikolọ ipinlẹ Ọyọ pada bọ sipo.

Nigba to n dupẹ lọwọ awọn eeyan naa, Gomina Makinde sọ oun ko tii jade kuro ninu iluu Ibadan, ati pe ilu Ibarapa ni Eruwa loun yoo kọkọo de, ko si sidi meji bi ko ṣe pe ifẹ toun ni si wọn lo fa a, nitori pe lọdun 2015 toun gbe apoti ibo gomina, awọn nikan ni wọn dibo foun.

O wa a jẹ ko ye gbogbo eeyan pe iṣẹ agbẹ ni wọn fẹẹ dojukọ lati loo fun igbelarugẹ ati idagbasoke awọn ohun meremere to wa nipinlẹ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI