ỌWỌ TẸ SUNDAY TO N FI ỌBẸ JALE KAAKIRI IJOKO ỌTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, June 16, 2019

ỌWỌ TẸ SUNDAY TO N FI ỌBẸ JALE KAAKIRI IJOKO ỌTA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Titi di asiko ti a kọ iroyin yi tan ni ko tii daju pe ọdọmọkunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Afọlayin Sunday ti wọni ni jibiti, gbajuẹ ati ole lo n ja kaakiri agbegbe Ijoko Ọta yoo bọ ninu wahala to ko ara rẹ sii.

Ati pe afaimọ ni ko ma lọọ ṣe faaji ẹwọn ọdun meje pere latari bọwọ ọlọpaa ṣe tẹ ẹ lẹyin ti wọn lo lọọ digun ja ọdọmọbinrin kan, Adeṣhina Ọmọlọla lole, to si tun ṣe e ṣibaṣibo.
 

Akẹkọọ jade ẹka ikẹkọọ Iṣiro/Kọmputa nile ẹkọ giga Adeniran Ogunsanya to wa lagbegbe Ijanikin, ipinlẹ Ekoo ni wọn pe Sunday, ati pe ọjọ kẹfa oṣu yi lọwọ tẹ ẹ.

Ohun ta a gbọ ni pe Sunday lọ si ṣọọbu ti wọn gba Ọmọlọla si, iyẹn nibi ti wọn ti n fi owo ranṣẹ, ti wọn si tun n gba owo (POS terminal), to si dibọn bi ẹni to fẹẹ gba owo nibẹ, wọn ni bo ṣe debẹ lo ti bẹrẹ sii wo ayika ṣọọ naa, to si rii pe Ọmọlọla nikan lo wa nitosi.

Lojiji ni wọn loo ki Ọmọlọla lọrun mọlẹ, to si yọ ọbẹ jade lati fi dunkooko mọ ọn, to tun ṣe e leṣe niwaju ori ati apa, nibi tiyẹn ti n du ẹmi ara rẹ. Lẹyin naa lo tọwọ bọ ibi ti wọn n ko owo sii, to si ko owo ti ko din ni ẹgbẹrun mejilelogogji (42,000) naira salọ.

Nibi ti wọn ni Ọmọlọla ri aaye dide nilẹ to wa lo ti sare jade, to si bẹrẹ sii pariwo ole lee lori, ko too di pe awọn to wa nitosi gba tọ ọ lẹyin, ti wọn si le e muu, bọwọ ṣe tẹ ẹ la gbọ pe wọn ko igbaju ati igbamu bo o.

Awọn kan la gbọ pe wọn gba wọn nimọnran pe ki wọn lọ fa a le awọn ọlọpaa Agbado lọwọ, ki wọn ma ba a luu pa, ti wọn si ṣe bẹẹ.

Ohun ta a ti ẹ tun gbọ ni pe nibi ti wọn ti n luu lọwọ lawọn kan ti de, ti wọn si fẹsun kan an pe ọjọ kẹtadinlogun, oṣu kẹrin ọdun yi lo lọọ ja Abimbọla Oyebolu lole, to si tun ja Ibrahim Oluwadamilọla lọjọ kọkanlelọgbọn oṣu karun, ti wọn loo gba foonu ati owo lọwọ pẹlu ipa, lẹyin to lu awọn eeyan naa tan.

Alukoro ile-iṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ jẹ ko ye wa pe loju ẹsẹ tọwọ tẹ ẹ ni wọn ti gba owo to ji ko naa lọwọ ẹ, ti wọn si tun gba ọbẹ to fi n jale naa pẹluu lọwọ ẹ.

Bẹẹ lo tun sọ fun wa pe ọga awọn, Bashir Makama ti sọ pe ko lọọ ṣe faaji diẹ lọdọ awọn ọlọpaa SARS digba ti yoo fi foju bale ẹjọ lati gba idajọ to tọ sii.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI