Ẹ BA MI DUPẸ LỌWỌ AARẸ BUHARI FUN BO ṢE BU ỌLA FUN BABA MI MKO - ỌMỌ ABIỌLA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 15, 2019

Ẹ BA MI DUPẸ LỌWỌ AARẸ BUHARI FUN BO ṢE BU ỌLA FUN BABA MI MKO - ỌMỌ ABIỌLA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Ọkan lara awọn ọmọ Oloogbe Mọshood Kaṣhimawo Ọlawale Abiọla, ẹni tawọn eeyan nigbagbọ pe oun lo jawe olubori ninu idibo Aarẹ tọdun 1993, Arabinrin Ọmọlọla Abiola-dwr ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Muhammadu Buhari pẹlu bo ṣe bu ọla, iyi ati ẹyẹ fun baba ẹ lẹyin ọdun mọkanlelogun to ti jade laye.

Bẹ o ba gbagbe, oriṣiriṣi ipa ni Aarẹ Buhari ko lati jẹ ki iranti Oloogbe MKO Abiọla wa niranti awọn ọmọ Naijiria kaakiri agbaye, to si tun sọ ọjọ kejila oṣu kẹfa ọdọọdun di ayajọ eto oṣelu awaarawa, atawọn min in bẹẹ.

Arabinrin Abiọla-Ẹdẹwọr tun wa a rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ Naijiria jakejado pe ki wọn ba oun gbe osuba nla fun Aarẹ Buhari, nitori pe titi lai niranti ẹ yoo fi wa ninu iran Abiọla atawọn ọmọ Naijiria.

Ninu atẹjade to pe ni ti obinrin naa gbe sita lọjọ Fraide ana, eyi to pe ni “JUNE 12 – President Muhammadu Buhari rekindles Nigeria’s Hope” lo ti jẹ ko di mimọ pe pẹlu awọn nnkan Aarẹ Buhari ṣe, o ti mu ki oku ọrun ti idibo ti wọn fagile naa lọọ sinmi ayeraye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI