NITORI AṢEYỌRI Ẹ NI JUVẸNTUS TO GBE SITA, RONALDO WỌ GAU LỌWỌ AWỌN OLOLUFẸ MESSI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, June 15, 2019

NITORI AṢEYỌRI Ẹ NI JUVẸNTUS TO GBE SITA, RONALDO WỌ GAU LỌWỌ AWỌN OLOLUFẸ MESSI

"Bi iṣu ẹni ba ta, wọn maa n fọwọ bo o jẹ ni" lọrọ to n tẹnu awọn ololufẹ ere bọọlu, paapaa awọn ololufẹ gbajugbaja agbabọọlu nni, Lionẹl Messi jade si ogbontarigi agbabọọlu nni, Cristiano Ronaldo lori bo ṣe gbe aṣeyọri ẹ ni Juventus jade lori ikanni ayelujara Instagram.

  
Bẹ o ba gbagbe, idije saa bọọlu to kọja ni Ronaldo kuro ni Real Madrid lọ si Juventus, tawọn ololufẹ Juventus si fi idunnu ati ayọ gba a wọle pẹlu nọmba keje ti wọn mọn ọn mọ.

  
Lai pẹ yi ni Ronaldo gbe e sori ikanni ayelujara Instgram pe oun dupẹ lọwọ Ọlọrun atawọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Juventus fun bi wọn ṣe gba oun wọle sibẹ lati darapọ mọ wọn, to si tun ka awọn aṣeyọri ẹ sibẹ.

  
Bawọn ololufẹ agbabọọlu Barcelona naa, Messi ṣe ri eyi ti wọn ti bẹrẹ sii ju oko ọrọ luu pe igberaga ẹ ti pọ ju, ati pe igba wo lo ri i ki Messi gbe iru nnkan bẹẹ sita lati maa fi yin ara ẹ.

  
Ṣugbọn lẹsẹkẹsẹ lawọn ololufẹ ọkunrin ọmọ Pọrtugal naa ti bẹrẹ sii da wọn lohun pe ki wọn ran ti wọn, nitori pe ko si nnkan to kan wọn bi ọkunrin naa ba n fi imọ-riri han.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI