Ẹ FURA O, AYEDERU MILIKI PEAK TI WA NITA O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ
Friday, June 28, 2019

Ẹ FURA O, AYEDERU MILIKI PEAK TI WA NITA O

A fi kawọn to fẹran lati maa mu miliki ọlọra to gbajumọ daadaa, iyẹn Peak ṣọra lati maa mọ iru eyi ti wọn yoo maa ra lọja latari bi wọn ṣe sọ pe ayederu ẹ ti wa lọja bayii, to si pọ ju ojulowo ẹ lọ.

Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin niroyin naa ti n tan kaakiri ori ayelujara.

Ṣugbọn lai pẹ yi la gbọ pe ọwọ ajọ to n yẹ awọn ojulowo ounjẹ ati oogun wo lorilẹ-ede yi, iyen NAFDAC pẹluu iranlọwọ awọn ọlọpaa rọwọ to iyaale ile kan ti wọn loun nigi lẹyin ọgba awọn to n ṣe ayederu miliki yi.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI