Ẹ MAA MURA SILẸ O, IJỌBA IPINLẸ OGUN FẸẸ BẸRẸ IGBANISIṢẸ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 28, 2019

Ẹ MAA MURA SILẸ O, IJỌBA IPINLẸ OGUN FẸẸ BẸRẸ IGBANISIṢẸ

A fi kawọn to n wa iṣẹ ijọba, paapaa awọn to ti kẹkọọ gboye nipinlẹ Ogun lọ maa gbaradi bayii, nitori pe ijọba ipinlẹ naa ti sọ pe eto igbanisiṣẹ yoo bẹrẹ laipẹ, ati pe ko din lẹgbẹrun mẹwaa oṣiṣẹ tawọn fẹẹ gba.

Eyi to n jẹ idunnu awọn araalu ninu gbogbo ẹ ni bijọba tun ṣe sọ pe kii ṣe pe awọn akẹkọọ  gboye nikan loun fẹẹ gba, bi ko ṣe pe gbogbo awọn to ba ni akikanju, yala, wọn ka iwe, tabi wọn ko gba ile ẹkọ kọja rara, ṣugbọn ti wọn mọ ọwọ yipada lawọn fẹẹ gba siṣẹ.

Akọwe iroyin Gomina, Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin lo gbe ọrọ naa sita lẹyin ipade ti Gomina Dapọ Abiọdun ṣe pẹlu awọn agbaagba ẹgbẹ oṣelu APC niluu Abẹokuta, nibi to ti mẹnuba ọrọ naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI