Ẹ MA ṢE SỌ IWA ỌMỌLUABI YIN NU LẸYIN ỌDUN ITUNNU AAWẸ - IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉTuesday, June 4, 2019

Ẹ MA ṢE SỌ IWA ỌMỌLUABI YIN NU LẸYIN ỌDUN ITUNNU AAWẸ - IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN

Oluwaṣeun Boye

Igbakeji Gomina ipinlẹ Ogun, Arabinrin Nọimọt Salakọ-Oyedele ti gbawọn musulumi kaakiri ipinlẹ Ogun, paapaa lorilẹ-ede Naijiria lamọnran pe ki wọn ma ṣe pa iwa ọmọluabi ti lẹyin ayẹyẹ ọdun Itunnu-Aawẹ to waye lonii.

O ni ki wọn ri i daju pe wọn n mu awọn ọrọ inu iwe mimọ ti Kuraani lo ni gbogbo igba, ki wọn ma si ṣe pada sinu awọn iwa buruku ti wọn ti gbe sọnu lasiko aawẹ wọ pada mọ, nitori pe ilana Ọlọrun lo yẹ ki wọn maa tọ.

Ilu Ọta ni igbakeji Gomina, Onimọ-ẹrọ Salakọ-Oyedele ti sọrọ naa lonii, lasiko to n bawọn ọmọ éyin Anọbi ṣajọyọ ayẹyẹ naa.


O lawọn iwa bi i ififun ni, riran awọn alaini lọwọ, iwa rere ati gbi gbadura lasiko to ba yẹ ni ki wọn tubọ maa tẹsiwaju ẹ, to si tun sọ pe gbogbo ẹ lo ni anfaani lọdọ Ẹlẹda.
 
Ninu waasi ẹ, Imaamu Agba ilu Ọta, Alaaji Sadeeq Buhari gbawọn Musulumi patapata lamọnran pe ki wọn awọn ẹkọ ti wọn kọ lasiko aawẹ Ramadaani lọ, bẹẹ lo rọ gbogbo awọn ọmọ ilu Awori jakdejado pe ki wọn rii daju pe wọn ṣagbatẹru ijọba tuntun yi, ki wọn le ṣe aṣeyọri.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI