TANKA EPO RỌBII ṢUBU L'ABẸOKUTA, LAWỌN ARAALU BA N FORI-GBARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 6, 2019

TANKA EPO RỌBII ṢUBU L'ABẸOKUTA, LAWỌN ARAALU BA N FORI-GBARI

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta
e lọrọ di boolọ o yago lọjọ Tọsde ọsẹ to kọja yi nigba ti wọn ni tanka elepo nla kan deede ṣubu lulẹ lojiji ladugbo Oke-Ṣokori niluu Abẹokuta ni nnkan bi aago mẹwaa kọja iṣẹju diẹ aarọ. 
Ko si nnkan meji to ko ibẹru sọkan awọn araalu, paapaa awọn ara agbegbe naa bi ko ṣe pe ọdun mẹjọ gbako ti tanka ṣubu lagbegbe naa ni eyi tun ṣẹlẹ. Ohun ta a gbọ ni pe ko ju bi ọjọ kẹta ti wọn bura fun Gomina ana nipinlẹ Ogun, Ibikunle Amosun tan, ni tanka naa ṣubu, to si jo ile ti ko din ni ogun ati ile epo nla kan ti wọn ṣẹṣẹ kọ sibẹ danu.
Ko din ni eeyan mẹẹdogun to ku sinu ijamba lọdun naa lọhun, tọpọ awọn eeyan si farapa yannayanna lasiko naa.
Ohun ta a gbọ ni pe agbegbe Itọṣi ni tanka ti wọn loo jẹ ileepo Dambold naa ti n bọ, to si n lọ si agbegbe Camp lati lọọ ja epo fun wọn, Ṣugbọn nigba to de agbegbe Ori-Omi ni Ṣokori lo ya soju ọna Ita-Ẹkọ, amọ ṣa, wọn ni bo ṣe n gun oju ọna naa to jẹ oke lọ, ni ijanu ẹ deede da iṣẹ silẹ, to si mu ẹyin pada.
Lẹsẹkẹsẹ ni ọdọmọkunrin kan toun maa n tẹle awọn awakọ tanka (motor-boy) ti sare bọ silẹ, to si bẹrẹ sii gbe igi sabẹ taya lati da a duro, ko ma baa da wahala silẹ, ṣugbọn ti ko pada ri tanka naa da duro.
Lẹsẹkẹsẹ lawọn mọto to n tẹle e lẹyin ti bẹrẹ sii mu ẹyin rin pada lati sa asala fun ẹmi ara wọn, ṣugbọn lojiji lo ṣubu lulẹ siwaju taisi kan, tawọn ero inu ẹ si ba ẹsẹ wọn sọrọ.
Bawọn to wa lagbegbe naa ṣe rii nkan to ṣẹlẹ yi lawọn eeyan ti bẹrẹ sii sa jade kuro ninu ile wọn, tawọn to ni ṣọọbu sitosi si sare ti ṣọọbu wọn, ti wọn na papa bora, ko too di pe wọn ranṣẹ pe awọn panapana lati wa duro nitosi.
Kopẹ ti wọn tun fi ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ mọnamọna pe ki wọn pa gbogbo ina agbegbe naa, ki wahala ma baa ṣẹlẹ.
AWIKONKO gbọ pe tori pe ọjọ Tọside naa jẹ ọjọ gbale-gbata (environmental) ni ko jẹ kawọn olounjẹ lagbegbe naa tete de lati dana ounjẹ, idi ni yii ti ko fi gbana, nitori ti wọn ni ko din ni olounjẹ mẹjọ to wa lagbegbe iṣẹlẹ naa.
Nnkan to tun fẹẹ ko ibẹru sọkan awọn eeyan ni bi olounjẹ kan to wa ladojukọ tanka to ṣubu yi ko ṣe tete ri ina ounjẹ pa, to si mu kawọn eeyan binu lọ ba a ni ṣọọbu lati luu, ṣugbọn tawọn oṣiṣẹ sifu difẹnsi gba a silẹ, ti wọn si le obinrin naa kuro ni ṣọọbu.
Lara awọn to kagbako ijamba ọdun mẹjọ sẹyin to b’AWIKONKO sọrọ nibi iṣẹlẹ naa to kọ lati darukọ ẹ sọ pe oun ko le gbagbe ọdun naa lọhun, tori pe ko din ni oṣu mẹfa toun lo lọsibitu pẹlu ọmọ oun kan, tawọn jona mọle, ṣugbọn to jẹ pe ori lo koun yọ.
Ohun tawọn eeyan n sọ ni pe ṣe kii ṣe pe afiṣe lọrọ naa to jẹ pe gbogbo igba ti wọn ba n bura fawọn gomina tuntun tan ni tanka epo maa n ṣubu lagbegbe naa, ati pe Ọlọrun lo ko awọn yọ lọwọ eyi ti ko jẹ ko gbana  lojiji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI