Ẹ WOJU ṢEUN TO FẸẸ DA WAHALA NLA SILẸ LỌJỌ TI WỌN BURA FUN GOMINA TUNTUN NIPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 6, 2019

Ẹ WOJU ṢEUN TO FẸẸ DA WAHALA NLA SILẸ LỌJỌ TI WỌN BURA FUN GOMINA TUNTUN NIPINLẸ OGUN

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ọgba SARS to wa ni Magbọn niluu Abẹokuta ni gendekunrin ẹni ọdun mọkanlelọgbọn kan, Oluwaṣeun Fakoyejọ wa to n bẹbẹ fun idariji latari bi wọn ṣe muu lọjọ Wẹside to kọja yi, lasiko ti wọn loun atawọn ẹmẹwa ẹ tawọn ti na papa bora da wahala silẹ nibi eto ibura ti wọn ṣe fun Gomina tuntun nipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun.

Ohun ta a gbọ ni pe ko too to asiko yi lawọn ọlọpaa ti gbọ pe awọn kan n gbero lati da wahala silẹ nibi eto naa, ti wọn si lawọn ọlọpaa naa ti gbaradi fun wọn lati fi ẹnikẹni tọwọ palaba ẹ ba segi jofin.

A gbọ pe bi eto naa ṣe n lọ lọwọ ni wọn lawọn kan ti n dọgbọn fẹhonu han, ṣugbọn to jẹ pe awọn ọlọpaa, sifu difensi atawọn fijilante ni wọn n da wọn lọwọ kọ, ko si pẹ ti wọn pari eto naa la gbọ pe wahala nla naa bẹrẹ ni pẹrẹu, tọrọ si di boolọ o yago.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe bi Gomina Abiọdun atawọn alejo ṣe lọ tan ni Ṣeun atawọn yooku ẹ ti bẹrẹ sii lu awọn eeyan, ti wọn si n fi awọn nnkan ija oloro halẹ mọ awọn eeyan lọjọ naa.

Lẹsẹkẹsẹ ni wọn lawọn kan ti ta awọn SARS lolobo, tawọn yẹn si sare de ibi iṣẹlẹ naa, ṣugbọn to jẹ pe bi wọn ṣe foju gan-an-ni awọn SARS ni wọn ti bẹrẹ sii ba ẹsẹ wọn sọrọ lẹyọkọọkan.

A ti ẹ gbọ pe wọn gbẹmi eeyan kan si Papa iṣere MKO to wa ni Kutọ nibi ti eto naa ti waye, ṣugbọn ti a ko pada ri okodoro dasiko ta a ṣakojọpọ iroyin yi tan.

Wọn ni lasiko ti Ṣeun n salọ ni wọn rọwọ too, ti wọn si ka ibọn ilewọ kekere kan mọ ọn lọwọ. Eyi gan nan ni wọn lo gbe de teṣan ọlọpaa to wa ni Magbọn, nibi to ti n gbaradi lati foju bale ẹjọ.

Agbẹnusọ fawọn ọlọpaa ipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe lootọ lọwọ tẹ Ṣeun, ti ọga wọn, Bashir Makama si ti paṣẹ pe wọn gbọdọ ṣe iwadii kikun lori ọdaran naa, ki wọn si rọwọ to awọn yooku ti wọn salọ, ki wọn too fẹsẹ ofin mu wọn.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI