AYỌ ABARA BINTIN: IYAWO YINKA AYEFẸLẸ BI IBẸTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉThursday, June 6, 2019

AYỌ ABARA BINTIN: IYAWO YINKA AYEFẸLẸ BI IBẸTA

Bo tilẹ jẹ pe iroyin to n lọ kaakiri ayelujara tẹlẹ ni pe iyawo gbajugbaja olorin nni, Dọkita Ọlayinka Joel Ayefẹlẹ ti bi ibẹta lẹẹkan ṣoṣo, to si ti tan kalẹ kaakiri pe lọọtọ ni, ṣugbọn olorin naa ti sọ pe ahesọ lasan niroyin naa jẹ.

Ilẹ Amẹrika la gbọ pe iyawo Yinka Ayefẹlẹ bimọ sii, tawọn eeyan si ti n ki ku oriire latigba naa pe ayọ abara bintin.

Bi iroyin naa ṣe n tan kalẹ lawọn eeyan fi to o leti pe ko wo nnkan tawọn eeyan tun n kọ nipa lasiko yi, eyi lo mu ki ọkunrin naa gba ori ayelujara abanidọrẹ ti fasibuuku ẹ lọ lati lọọ kọ ọ sibẹ pe ki wọn di eti si ahesọ ti jẹ otitọ.

Fọto kan ni Yinka Ayefẹlẹ fi da awọn eeyan lohun, tawọn eeyan si bẹrẹ sii sọ pe adura ti yoo wa si imuṣẹ laipẹ ni wọn n gba fun silẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI