Bi
ijọba tuntun ṣe ti bẹrẹ nipinlẹ Ogun, Apapọ Ẹgbẹ awọn wọnlẹ-wọnlẹ
lorilẹ-ede Naijiria, ẹka tipinlẹ Ogun, iyẹn Nigerian Institution of
Surveyors ti sọ pe digbi lawọn wa lẹyin ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ati igbakeji rẹ, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, ati pe awọn ṣetan
lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹ.
Ninu
atẹjade ti awọn mẹrin fọwọ sii, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lai pẹ yi
ni wọn ti jẹ ko di mimọ pe awọn ti ṣetan lati mu idagbasoke ba ipinlẹ
Ogun nipa ṣiṣagbatẹru ijọba tuntun naa.
Awọn
mẹrin naa ni Surv. Babatunde Ashaye to jẹ alaga apapọ; Sur Adewale
Oluwafẹmi, alaga awọn aladani; Ọnọrebu (Sur) Lanre Ṣotayọ to jẹ akọwe
ẹgbẹ lapapọ ati Sur Babatunde Ogunlami toun jẹ akọwe awọn aladani.
Wọn
jẹ ko di mimọ pe awọn ti wa ni imurasilẹ lati mu ipinlẹ naa gun oke
agba nipa ṣiṣagbatẹrun awọn eto to ba jẹ mọ iṣẹ ilẹ wiwọn, ati pe gbogbo
nnkan ti Gomina Dapọ Abiọdun ba n fẹ lawọn yoo tẹle lati rii pe
ilọsiwaju rere de ba ipinlẹ Ogun.
Bakan naa ni wọn wa a tun fi kun ọrọ wọn pe bi igbega ati idagbasoke ṣe jẹ ijọba Dapọ Abiọdun logun naa jẹ ẹgbẹ NIS logun nitori pe igbega ati idagbasoke lo le mu eto ọrọ aje ipinlẹ tabi orilẹ-ede dagba soke.
No comments:
Post a Comment