SANWO-OLU BURA FUN ADAJỌ AGBA NIPINLẸ EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 13, 2019

SANWO-OLU BURA FUN ADAJỌ AGBA NIPINLẸ EKOO

Ọlaide Ọṣinuga, Eko  
Gomina Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Ekoo ti bura fun adajọ agba tuntun ti yoo tukọ ẹka eto idajọ nipinlẹ naa. Aarọ oni Tọside ni Gomina Sanwo-Olu bura fun Onidajọ Kazeem Alọgba.

Sanwo-Olu sọ pe ọna lati dẹkun awọn ọdaran lawọn ọgba ẹwọn nipinlẹ Ekoo lo mu koun yan ẹni to ṣe e fọkan tan, iyẹn Onidajọ Alọgba.

Bẹẹ lo ṣeleri pe oun yoo fọwọsowọpọ pẹluu ẹka eto idajọ naa, ati ijọba apapọ lati riipe iṣẹ n lọ niṣẹju-iṣẹju lai dawọ duro, paapaa lawọn opopona, lati rii pe ofin irinna n fẹsẹ mulẹ.



Siwaju sii lo dupẹ lọwọ adajọ agba tẹlẹ, Onidajọ Ọpẹyẹmi Ọkẹ fun ipa ribiribi to ti ko lẹka eto idajọ nipinlẹ Ekoo, to si tun ṣeleri pe ijọba ipinlẹ naa ko nii gbagbe ẹ.

Ninu ọrọ ti ẹ, Onidajọ agba naa sọ pe oun yoo maa duro de iranlọwọ ijọba lati rii daju pe awọn amuyẹ to ba nilo lawọn yoo ṣe.

Bakan naa lo tun sọ pe oun yoo lo ipo naa lati rii pe wọn pana iwa ajẹbanu patapata.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI