EYI NI B'AWỌN ỌTA ṢE FARAHAN ANTHONY JOṢHUA NI USA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, June 2, 2019

EYI NI B'AWỌN ỌTA ṢE FARAHAN ANTHONY JOṢHUA NI USA

Ṣàǹgbà fọ́ lánàá nígbà tí Andy Ruiz ọmọ Ilẹ̀ Mexico fi ẹ̀ṣẹ́ àràmàǹdà kan fọ́ kèrékèré Anthony Joshua níbi ìjà ẹ̀ṣẹ́ kíkàn tó wáyé ní Madison Square Garden ni USA. 
Ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Ruiz fi ẹ̀ṣẹ́ dá Ọ̀gbẹ́ni náà dọ̀bálẹ̀ tí kò sì rí nǹkan ṣe síi. Ń ṣe ló dà bí pé ẹ̀ṣẹ́ Ruiz ń kọ́ Anthony Joshua lóòyì. Èyí ló fà á tí àwọn kan fi sọ wípé bóyá ni kìí ṣe àwọn ará Abúlé rẹ̀ ní Ṣagamu ló gba àbòdè fún-un. Wọn ní nígbà tí òun náà kò wálé láti wá gba àjẹsára.
Ṣùgbọ́n àwọn kan tún sọ pé Jóṣúà mọ̀ọ́mọ̀ fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ni, àti pé eléyìí yíò mú kí owó ńlá bọ́ sí ọwọ́ rẹ̀ nígbà tí wọn bá fẹ́ẹ́ tún ìjà náà jà. Mọ̀jà mọ̀sá làá mọ akíkanjú l'ógun.


- Ìròyìn Àdíndùn
 

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI