ṢỌỌṢI ILẸ ADULAWỌ ṢE IRANLỌWỌ FUN ỌGỌTA OPO, BẸẸ NI WỌN TUN GBE IRANLỌWỌ DIDE FUN AKANDA EEYAN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, June 2, 2019

ṢỌỌṢI ILẸ ADULAWỌ ṢE IRANLỌWỌ FUN ỌGỌTA OPO, BẸẸ NI WỌN TUN GBE IRANLỌWỌ DIDE FUN AKANDA EEYAN


Ọlaide Ọṣinuga, Eko - Omije ayọ lo n jabọ loju awọn opo ti ko din lọgọta, ati Arabinrin kan to jẹ akanda eeyan lonii nigba ti ṣọọsi ilẹ Adulawọ nni, The African Church Solution Ground to wa lagbegbe Lẹmẹ niluu Abẹokuta ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.


AWIKONKO gbọ pe Arabinrin Fẹyintọla Ayede ni akanda eeyan naa ti wọn fun lẹgbẹrun ogun (20,000) naira ati ẹrọ ijata kan ṣoṣo pe ko maa fi gbọ bukata ara rẹ, paapaa nigba ti wọn lawọn eeyan ko fẹẹ ran an lọwọ.

Yatọ si eyi, ṣọọṣi naa tun fi ẹbun irẹsi (rice) ta awọn opo ti ko din lọgọta lọrẹ nibi isin idupẹ awọn ọkunrin ati obinrin oore-ọfẹ (Sons and Daughters of Grace).

Pabanbari ẹ ni bi wọn tun ṣe kede pe wọn yoo maa fun Arabinrin Fẹyintọla lowo ti ko din ni ẹgbẹrun mẹẹdogun (15,000) naira loṣooṣu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI