EYI NI BI ỌKỌ ATI'YAWO ṢE PADANU ẸMI WỌN L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 8, 2019

EYI NI BI ỌKỌ ATI'YAWO ṢE PADANU ẸMI WỌN L'ABẸOKUTA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta

Fun bii wakati meji gbako lawọn mọto ko fi le kọja lọjọ Tọside ijẹta ladugbo kan ti wọn n pe ni Aṣero nigba ti tirela nla kan yiwọ mọ ọlọkada kan lẹnu, to si tẹ tọkọ tiyawo to wa lori ọkada naa gẹgẹ bi ero pa loju ẹsẹ.

Gẹgẹ bi iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ, wọn ni ilu Ibadan ni tọkọ tiyawo naa ti n bọ, ti wọn si bọọlẹ ni garaaji Ibadan to wa ni Aṣero. Bi wọn ṣe bọ silẹ tan, la gbọ pe baale ile kan ti wọn n pe ni Gbenga (ta a fi orukọ baba ẹ pamọ) ti wọn ni ọkada lo fi n ṣiṣẹ lọọ ba wọn lati gbe wọn.

Ko pẹ ti wọn lawọn tọkọ tiyawo yi gun ọkada naa ni wọn bọ sọna, bi wọn ṣe maa de iwa ile ẹkọ girama Ẹgba Comprehensive la gbọ pe tirela nla kan toun n kọja lọ deede jawọ fun koto kekere kan.

Ojiji ni wọn ni ẹni to wa tirela naa jawọ fun koto yi, to si kọlu ọlọkada toun fẹẹ yiwọ jade lẹgbẹ ẹ, loju ẹsẹ ni wọn ṣubu sinu koto, nigba to si maa mọ nnkan to n ṣẹlẹ, o ti fi taya tẹ tọkọ-tiyawo naa lori mọlẹ.

Ariwo ti wọn ni ẹni to wa tirela IVECO ti nọmba idanimọ ẹ jẹ SRA 757 XA naa gbọ lo mu ko duro, nigba to si maa mọ nnkan to n ṣẹlẹ, o rii pe oun ti paayan, loju ẹsẹ la gbọ pe o ti ba ẹsẹ rẹ sọrọ.

 
Ko pẹ tiawọn lawọn eeyan fi ranṣẹ sawọn oṣiṣẹ oju popona, iyẹn TRACE lati wa a wo nnkan to ṣẹlẹ, awọn la si gbọ pe wọn ko awọn oku tọkọ-tiyawo naa lọ si mọṣuari ọsibitu Ijaye.

AWIKONKO gbọ pe awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ni wọn gbe Gbenga ti wọn ni mọto lo n fọ l'Aṣero, to si tun n fi ọkada ṣiṣẹ naa lọ si ọsibitu to ti n gba itọju, nitori ti wọn loun naa kan lẹsẹ, ṣugbọn tori ko ba a ku ni wọn ṣe sare gbe e lọ.

Bo tilẹ jẹ pe awọn to wa tirela naa ba ẹsẹ wọn sọrọ loju ẹsẹ, ṣugbọn iyalẹnu ni wọn loo jẹ nigba ti alukoro ajọ TRACE, Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi sọ pe ṣe ni ọlọkada naa tun salọ pẹluu, tawọn eeyan si sọ pe kii ṣe bọrọ ṣe ṣẹlẹ lo ṣe sọ ọ.

Lara awọn to gbe iroyin naa si wa leti jẹ ko ye wa pe oju awọn niṣẹlẹ naa ṣe waye, ati pe lẹyin bii wakati meji lawọn oṣiṣẹ TRACE ṣẹṣẹ de ibi iṣẹlẹ, nigba ti wọn si maa dẹ, oku awọn meji naa ni wọn ba nilẹ, eyi ni wọn loo jẹ ki wọn ro pe ọlọkada ti salọ.

Ọgbẹni Babatunde Akinbiyi tun jẹ ko di mimọ pe awọn ti wa tirela ati ọkada naa lọ teṣan ọlọpaa to wa ni Ọbantoko.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI