WỌN L'AṢIRI ỌLỌKADA TO FẸẸ JI EEYAN GBE TU L'ABẸOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSaturday, June 8, 2019

WỌN L'AṢIRI ỌLỌKADA TO FẸẸ JI EEYAN GBE TU L'ABẸOKUTA

Bọsun Ọlaniyi, Abẹokuta 

"Ẹ ma jẹ ki iya yi jẹ wa gbe" lọrọ ẹbẹ ti wọn lo n tẹnu idile Adeyinka kan niluu Abẹokuta n bẹ ijọba pe ki wọn ṣaanu awọn lati ma ṣe jẹ kawọn ọlọpaa fọwọ ọla gba wọn loju, latari awọn iwa ti wọn n hu, ki wọn si jẹ ki idajọ ododo fẹsẹ mulẹ.

Kani ki i ṣe pe awọn ẹlẹyinju aanu kan ti wọn tete dide lati ma ṣe jẹ kawọn eeyan ṣe idajọ lọwọ ara wọn ni, boya wọn ki ba ti lu ọdọmọkunrin ọlọkada kan pa lọsan onii, Satide latari baṣiri ẹ ṣe tu pe o fẹẹ ji ọmọdebinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun (17) gbe.

Gẹgẹ b'AWIKONKO ṣe gbọ, ni nnkan bi aago mẹwaa aarọ oni la gbọ pe iyaale ile kan, Arabinrin Bọlaji Adeyinka ran ọmọ ẹ, Ajọkẹ ọmọdun mẹtadinlogun niṣẹ lati ṣọọbu ẹ to wa ladugbo Car Wash si adugbo Aṣero niluu Abẹokuta.

Bọmọ naa ṣe kuro nibi ti mama ẹ ran an lo n pada si ṣọọbu mama ẹ lati lọọ jiṣẹ to ran an, ẹgbẹ titi nitosi ṣọọṣi MFM, Aṣero ti wọn ni Ajọkẹ ti n wa mọto ti yoo gbe e de Car Wash ni wọn sọ pe ọlọkada kan toun n kọja lọ ti duro niwaju ẹ pe oun mọn ọn rii, ko si jẹ koun gbe e de Car Wash to n lọ.

Kayeefi ni wọn loo jẹ fun Ajọkẹ nigba to ri ẹni ti komọ rii, to si pada gba lati jẹ ki ọlọkada naa gbe oun. Ṣugbọn ṣe lọrọ yi pada nigba ti wọn ni ọlọkada naa yawọ papa iṣere Muda Lawal lojiji lai sọ nnkankan fun Ajọkẹ.

Ibeere ta a gbọ pe Ajọkẹ kọkọ beere ni pe 'Nibo lẹ n gbe mi lọ, ọna Car Wask ko lẹ gba yi', ti wọn si ni ọlọkada naa ko dahun. Eyi ni wọn loo jẹ ki Ajọkẹ ki ariwo mọlẹ, to si bẹrẹ sii ke gbajare sawọn eeyan pe ki wọn gba oun.
Ere lawọn ti wọn ri ọlọkada yi ati Ajọkẹ kọkọ pe e, afi bi wọn ṣe sọ pe lojiji Ajọkẹ bẹ silẹ lori ọkada, to si farapa yanna-yanna, eyi gan an ni wọn loo jẹ kawọn to wa nitosi sare dide lati mọ pe ọrọ naa ki i ṣe ere rara.

Bawọn eeyan ṣe dide la gbọ pe ọlọkada naa fẹsẹ fẹẹ, tawọn eeyan si tun sare gbe ọkada min in fi lee, ko too di pe wọn pada rii mu.

Nigba tọwọ tẹ ẹ, gbogbo bi wọn ṣe sọ pe wọn n beere ọrọ lọwọ ẹ ni wọn ni ko ri ọrọ gidi kan sọ, ti wọn si sọ pe ibi lawọn to wa nibẹ fi fẹẹ maa luu ni wọn lawọn kan sọ pe kiwọn lọọ fa a le awọn ọlọpaa Ọbantoko lọwọ lati gbe igbesẹ to ba tọ labẹ ofin.

Bi wọn ṣe mu ọlọkada naa de teṣan ọlọpaa la gbọ pe awọn ọlọpaa ti beere ọrọ lọwọ ẹ, ti wọn si tun gba akọsilẹ ẹ. Bẹẹ la gbọ pe wọn mu Ajọkẹ lọ osibitu Olikoye lọọ gba itọju pẹlu bo ṣe farapa.

Ohun ti wọn lo n jẹ kọrọ naa su awọn obi Ajọkẹ lọwọ ti wọn lawọn ọlọpaa n yọ, paapaa nigba ti wọn lawọn ọlọpaa lọọ yẹ ile ọlọkada naa wo, ti wọn ko ba nkankan nibẹ, ni wọn n jẹ ko ye awọn obi Ajọkẹ pe awọn yoo fi ọlọkada naa silẹ lati maa lọ layọ ati alaafia, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Nigba to n b'AWIKONKO sọrọ, Ajọkẹ sọ pe "Mi o mọ buọda yẹn ri rara, ṣugbọn wọn lawọn mọ mi lo jẹ ki n gba pe ki wọn gbe mi, ibi ti wọn ti n gbe mi lọ ni wọn ti ya sinu papa iṣere MKO to wa ni Aṣero. Mo beere pe ibi ti mo n lọ kọ ni wọn ya si, ṣugbọn ko da mi lohun, idi ni yii ti mo fi pariwo.

"Igba ti mo pariwo, ko tun dahun, eyi lo mu mi bẹ silẹ lori ọkada, tawọn to wa nibẹ si ba mi pariwo lee lori. Awọn to wa nibẹ lo sọ pe ki wọn mu ọlọkada yẹn daadaa, pe wọn ti n ṣe tipẹ. O dami loju pe wọn fẹẹ ji mi gbe ni. Mi o mọ nnkan tawọn ọlọpaa sọ tori pe mi o si nibẹ nigba ti wọn n beere ọrọ lọwọ ẹ. Mo fẹ kawọn ọmọ Naijiria mọ pe ọlọkada."

Iya Ajọkẹ, Arabinrin Bọlaji sọ pe "Emi ni mo ran ọmọ mi Ajọkẹ lọ si Car Wash, ṣadede ni mo ri ti ẹnikan pe mi pe ṣe emi ni Mama Ajọkẹ, ti mo si da wọn lohun pe bẹẹni, wọn ki n maa bọ ni Aṣero. Oju ẹsẹ ni mo ti debẹ, igba ti mo maa debẹ, mo ti bawọn eeyan rẹpẹtẹ nibẹ, ti wọn si ṣalaye nnkan to ṣẹlẹ fun mi.

"Inu papa iṣere Muda Lawal ko jẹ mọ ọna Car-Wash rara, nigba ta a si tun beere ọrọ lọwọ ẹ pe ki lo de to fi wọnu ibi to wọ lọ lai sọ fun ọmọ mi, nnkan to sọ ni pe oun fẹẹ fun ẹni kan ni ṣenji (change) nibẹ ni, ṣugbọn mi o gbagbọ rara, irọ ni.

"Awọn ọlọpaa beere pe ki la fẹ, a si jẹ ko ye wọn pe a fi ka lọ si kọọtu, nitori pe adajọ lo le fidi ẹ mulẹ pe kii ṣe gbọmọgbọmọ. Ọjọ Sande ọla lawọn ọlọpaa sọ pe ki a wa si teṣan lati tẹsiwaju."

Obinrin naa jẹ ko di mimọ pe bawọn ọlọpaa naa ṣe n sọrọ ti n fi han pe wọn fẹẹ da oju ọrọ naa ru ni, ti wọn si n bẹbẹ pe kawọn ọmọ Naijiria gba awọn.

Ohun tawọn kan ti ẹ n sọ ni pe o ṣeeṣe ko jẹ pe ọlọkada naa fẹẹ fipa ba Ajọkẹ sun ni, ko ma jẹ pe ṣe lo fẹẹ ji i gbe.

Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ fawọn ọlọpaa, Ọgbẹni Abimbọla Oyeyẹmi sọrọ lo si pabo dasiko ta a kọ iroyin yi tan. A pe ọkunrin naa titi, ko gbe foonu ẹ.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI