ỌWỌ ỌLỌPAA TI TẸ JẸNẸRA O, OGBOLOGBO ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN L'EKOO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 8, 2019

ỌWỌ ỌLỌPAA TI TẸ JẸNẸRA O, OGBOLOGBO ỌMỌ ẸGBẸ OKUNKUN L'EKOO

Ọlaide Ọṣinuga, Eko 

Adura tawọn ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ekoo n gba bayii ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki gbajugbaja olori ọmọ ẹgbẹ okunkun nipinlẹ Ekoo, Tusuf Omidele tawọn eeyan tun n pe ni Jẹnẹra pada sile layọ ati alaafia, tawọn min in si tun n rawọ ẹbẹ sawọn ọlọpaa atijọba apapọ ni pe ki wọn juu sẹwọn gbere latari awọn ẹmi toun naa ti fi ṣofo danu.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, Yusuf ti inagijẹ rẹ n jẹ Jẹnẹra yi pẹlu awọn ọmọ ẹyin ẹ mọkanlelogun la gbọ pe ọwọ awọn ọlọpaa tẹ niluu Ikorodu lasiko ti wọn n fọ ilu mọ kuro lọwọ awọn ọbayejẹ.

 
Awọn ọlọpaa kogberegbe la gbọ pe wọn mu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Ẹyẹ naa, ti wọn si ti foju wọn han fawọn araalu pe asiko re e ti wọn le sun daadaa, ki wọn si diju mejeeji.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI