EYI NI BI WỌN ṢE LE NEYMAR KURO NINU IDIJE KỌPA AMẸRIKA - IROYIN AWIKONKO

EYI NI BI WỌN ṢE LE NEYMAR KURO NINU IDIJE KỌPA AMẸRIKA

PIN-IN KAAKIRI
Iroyin ti ko dun mọ gbogbo awọn ololufẹ gbajugbaja agbabọọlu nni, Neymar ninu ni bi wọn ṣe kan an lẹsẹ nibi ifigagbaga ọlọre-sọrẹ ẹgbẹ agbabọọlu orilẹ-ede Brazil pẹlu Qatar, nibi ti Brazil ti pọ ata soju Qatar nipa aami ayo meji si odo.

Ori papa naa ni Ney,mar ti farapa gidi-gan an, to si mu ki egungun orunkun ẹ yẹ sẹgbẹ kan, eyi ti wọn ni yoo lo ọpọlọpọ oṣu lati fi gba itọju ko too le pada sori papa iṣere bọọlu.

Awọn to n ṣagbatẹru idije bọọlu Brazilian Football Confederation (CBF) lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ pe Neymar ko ni lanfaani lati kopa lasiko.

Ibanujẹ nla la gbọ pe o ti ko gbogbo awọn ṣagbatẹru idije South American continental championship to n bọ lọna sii, nitori pe ọkunrin ọmọ orilẹ-ede Brazil naa ni wọn nifẹ si juu ninu gbogbo awọn to fẹẹ kopa patapata.

Ko ju bi oogun iṣẹju ti wọn bẹrẹ ifigagbaga pẹlu orilẹ-ede Qatar la gbọ pe wọn ṣe Neymar leṣe lori papa, ti wọn si yọọ jade lẹsẹkẹsẹ, iyẹn lalẹ ana, Wẹside lori papa Brasilia’s Mane Garrincha.

No comments:

Post a Comment

PIN-IN KAAKIRI