BANKI ACCESS WỌ GAU, ONIBAARA GBE WỌN LỌ SILE ẸJỌ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 6, 2019

BANKI ACCESS WỌ GAU, ONIBAARA GBE WỌN LỌ SILE ẸJỌ

Ọkan lara awọn onibaara Banki kan to gbajumọ daadaa, iyẹn Access Bank ti gbe banki naa lọ sile ẹjọ, to si n beere obitibiti owo fun bi wọn ṣe sọ awọn iwe dukia ẹ to fi ya owo nu.

Iroyin to tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko ye wa pe ọkunrin kan ti orukọ rẹ n jẹ Isaac Dare la gbo pe o ya owo lọwọ Banki naa lọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹwaa ọdun 2013, to si fi ile ati dukia ẹ to wa lagbegbe Oshodi/Isọlọ ti ko din ni miliọnu miliọnu lọna ọgọfa ati ẹgberun mẹrin din ẹ (N123.758m) naira duro.

Ohun to jẹ iyalẹnu ni pe ilẹ ẹjọ giga to fikalẹ siluu Abuja ni Ọgbẹni Isaac gbe Banki Access lọ, to si fẹsun kan wọn pe wọn sọ awọn iwe dukia oun nu, to si tun ṣapejuwe iwa naa gẹgẹ bi aibikita.

Isaac wa a bẹbẹ pe kile ẹjọ paṣẹ pe ki Banki naa san owo itanran miliọnu lọna aadọfa ati ẹgbẹrun meji (N112m) naira.

Ẹkunrẹrẹ iroyin naa re e: WỌN GBE BANKI ACCESS LỌ SILE ẸJỌ


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI