EYI NI BI WỌN ṢE TU DAYỌ, ỌMỌ MISITA SILẸ LỌWỌ AWỌN AJINIGBE LẸYIN WAKATI MẸRINLELOGUN - IROYIN AWIKONKO

YÀJÓ-YÀJÓ
Wednesday, June 19, 2019

EYI NI BI WỌN ṢE TU DAYỌ, ỌMỌ MISITA SILẸ LỌWỌ AWỌN AJINIGBE LẸYIN WAKATI MẸRINLELOGUN

 
Gbogbo awọn alabayọ ni wọn ti n ba minisita tẹlẹri fun eto ilera lorilẹ-ede Naijiria, Ọjọgbọn Isaac Adewọle yọ latari bi ọmọ ẹ, Dayọ Adewọle ṣe gba itusilẹ lọwọ awọn ajinigbe ti wọn ji i gbe nirọlẹ ana Tuside. 
 
Bo tilẹ jẹ pe ko tii sẹni to ti i mọ boya owo ni wọn fi gba a silẹ, tabi pe wọn kan tuu silẹ lasan ni, sibẹ ṣe lawọn eeyan n ki ọkunrin naa ku oriire ti idalare naa, ati pe wọn ko da ẹmi ẹ legbodo lojiji.

Owurọ Ọjọru ni iroyin gbe e jade pé lójúnà oko ni wọ́n ti jí Deji Adewole gbe ní ìlú Fiditi, ipinlẹ Oyo.

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ ti mu afurasi mẹta to jẹ osisẹ ni oko ti wọn ti ji Dayo Adewole, to jẹ ọmọ minisita fun eto ilera tẹlẹri Isaac Adewole naa gbe.

Alukoro ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Ọyọ, Olugbenga Fadeyi ni kete ti isẹlẹ naa waye, ni wọn ti bẹrẹ iwadii, ti wọn si ti ri ọkọ mejeeji ti wọn fi ji ọmọ minisita naa gbe ninu igbo, ti wọn si ti gba a pada.

O fikun wi pe, awọn ajinigbe naa ko i ti i kan si ẹbi ati ara ẹni ti wọn jigbe. Bakan naa ni wọn ko i tii beere owo itusilẹ ni ọwọ awọn ẹbi.

Alukoro ile isẹ ọlọpaa naa wa rọ awọn ara ilu, lati ran awọn lọwọ lati fi iroyin lede ti wọn ba gbọ nkankan, nitori awọn ọlọpaa gbagbọ wi pe awọn ajinigbe yii n gbe laaarin awọn eniyan ninu ilu.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI