GBOGBO AGBAYE LO N ṢAYẸYẸ ỌJỌ IBI GBAJUMỌ PEDEPEDE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 20, 2019

GBOGBO AGBAYE LO N ṢAYẸYẸ ỌJỌ IBI GBAJUMỌ PEDEPEDE


Bi ẹ ṣe n ka iroyin ni gbogbo awọn eeyan patapata kaakiri aggbaye, paapaa lorilẹ-ede Naijiria ni wọn n fi atẹjiṣẹ oriṣiriṣi ranṣẹ si ọkan pataki lara awọn ilu mọn ọn ka sọrọsọrọ nni, Ibrahim Kẹhinde Iṣọla tawọn eeyan mọ si Van Garuba lati fi kii ku ayẹyẹ ọjọ to n ṣe lonii, ogunjọ oṣu kẹfa.

Odu ni Van Garuba, kii ṣaimọ foloko lagboole pedepede lorilẹ-ede Naijiria, paapaa nipinlẹ Ogun to fi ṣebugbe, to si jẹ pe ọkan pataki lara awọn pedepede to ṣẹṣẹ n dide bọ nidi iṣẹ naa ni.

Ko sẹni to gbọ lara awọn eto ẹ to maa n ṣe lawọn ori redio nipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Ọyọ ti wọn kii gbe oṣuba kare fun un, idi ni yii tawọn olugbọ redio fi n kan saara sii pe ọkin jọba laarin awọn ẹyẹ.

Adẹrinpoṣoonu Ọmọ bibi ilu Ilọrin to dagba sipinlẹ Ọyọ naa lo jẹ pe pupọ awọn agba nidi iṣẹ naa ni wọn maa n fẹ baa ṣe pọ latari awọn agbekalẹ ẹ ti ko ni aṣaaju to fi n ṣeto kaakiri ile-iṣẹ redio.

Bo ṣe gbajumọ laarin awọn ẹgbẹ sọrṣorṣo naa lo tun jẹ odu laarin ẹgbẹ oni tiata atawọn olorin patapata.

Lati ana tii ṣe Wẹside la gbọ pe awọn ololufẹ ẹ ti n fi atẹjiṣẹ ranṣẹ sii, ko da a ta a tun gbọ pe ṣe lawọn eeyan n fi owo taaka laarin ara wọn lati kọkọ mọ ẹni ti yoo kii lonii fun ọjọ ibi naa.

Bi ẹ ba ṣi redio yin bayii, o fẹẹ le jẹ pe ko si ile-iṣẹ redio kan ṣoṣo ti wọn ko ti nii kii ku oriire ọjọ ibi ẹ, tori pe latigba ti aago mejila aarọ oni ti lu lawọn ile-iṣẹ redio ti n kii, ko da ti wọn tun gbe orin tawọn kan fi mọ riri ẹ sori afẹfẹ.

Ile-iṣẹ AWIKONKO MEDIA CHANNEL to n gbe Iroyin Awikonko jade sita naa wa n lo asiko yi lati fi mọ riri ipa ti ọkunrin naa n ko lori ile-iṣẹ wa, tori pe ọkan pataki lara awọn to n gbe ile-iṣẹ wa larugẹ ni Van Garuba jẹ.

Aṣeyiṣamọdun, ti a si n gba a ladura pe igbega ni yoo ma a jẹ ti ẹ ni gbogbo ọjọ aye ẹ. Ẹni to ba ri Van Garuba, ko ba wa kii daadaa pe ‘igba ọdun, iṣẹju aaya kan ni fun un’.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI