GBOGBO AWA AṢOJU-ṢOFIN FỌKANBALẸ LORI GBAJABIAMILA-WASE - ỌNỌREBU TUNJI-OJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, June 9, 2019

GBOGBO AWA AṢOJU-ṢOFIN FỌKANBALẸ LORI GBAJABIAMILA-WASE - ỌNỌREBU TUNJI-OJO

Bi yiyan olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin tuntun niluu Abuja ṣe ti n sunmọ etile, iyẹn bi yoo ti ṣe waye lọjọ Tuside ọsẹ tuntun ta a fẹẹ wọ yi, gbogbo awọn eeyan kaakiri ni wọn ti n fi idunnu wọn han lori Ọnọrebu Olufẹmi Gbajabiamila, to jẹ olori ọmọ ẹgbẹ aṣoju-ṣofin to pọ ju tẹlẹ lorilẹ-ede Naijiria.

Ohun a  gbọ ni pe gbogbo ọmọ ile igbimọ aṣofin patapata ti wọn dibo yan siluu Abuja ni wọn ti n sọ pe ko sẹni meji tawọn n fẹ, bi ko ṣe Ọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila gẹgẹ bi olori wọn, ti Ọnọrebu Ahmẹd Idris Wase yoo si jẹ igbakeji rẹ nile igbimọ aṣofin kẹsan an lorilẹ-ede Naijiria.

Ninu atẹjade ti Ọnọrebu Olubunmi Tunji-Ojo ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan lati ṣoju ẹkun Akoko North East ati Akoko North West nipinlẹ Ondo fi n gba ẹnu gbogbo awọn aṣoju-ṣofin fi sita, eyi to tẹ AWIKONKO lọwọ lonii lo ti jẹ ko di mimọ pe ko sẹni to ni iwa mimọ to Ọnọrebu Gbajabiamila ninu itan awọn aṣoju-ṣofin.

Ọnọrebu Olubunmi Tunji-Ojo sọ pe ko si itan tabi akọsilẹ kankan to le fidi ẹ mulẹ pe Ọnọrebu Gbajabiamila tawọn eeyan fọwọ lati di olori ile igbimọ aṣoju-ṣofin lọwọ si iwa ibajẹ, tabi iwa jẹgudujẹra, to si jẹ pe iru eeyan bẹẹ lawọn n fẹ lati dari awọn eeyan lorilẹ-ede Naijiria.
O sọ siwaju pe "Bi gbigbe ile igbimọ aṣofin kẹsan an ati tawọn alakoso ti yoo tukọ ẹ ṣe ti n sun mọ etile bayii. Awa ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin kẹsan an ni idaniloju pe a fẹẹ fitan tuntun balẹ lọjọ Tuside, ọjọ kọkanla oṣu kẹfa ọdun 2019 pe ifẹ apapọ orilẹ-ede Naijiria lo bori tawọn to ku. A gbọdọ rii daju pe a fọwọsowọpọ lati yan awọn olori ti yoo tukọ ijọba rere, nipa ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu awọn ti yoo gbe orilẹ-ede yi larugẹ.
Ọnọrebu Olubunmi Tunji-Ojo
"Awa ti a jẹ ọmọ ile igbiumọ aṣoju-ṣofin kẹsan an layọ ati anfaani lati sọ pe, iyẹn awa ọmọ ẹgbẹ ti o pọ ju lọ ti mu awọn ti a nigbagbọ ninu wọn pe wọn kun oju oṣuwọn kaakiri, ti a si ti bu ọwọ lu wọn lati dari ile igbimọ wa, nitori pe nipa wọn ni ifẹ gbogbo awọn eeyan yoo fi wa si imuṣẹ.

"Gbogbo awa aṣoju-ṣofin kaakiri gbogbo ẹgbẹ oṣelu la yan Ọnọrebu Gbajabiamila ati Ọnọrebu Wase gẹgẹ bi olori ati igbakeji, to si jẹ pe gbogbo awọn gomina ti wọn gbe ijọba silẹ, atawọn gomina tuntun lẹgbẹ oṣelu APC ati ẹgbẹ oṣelu alatako ni wọn bu ọwọ lu ipinu yi. Ati pe yiyan naa tun ni ontẹ Aarẹ orilẹ-ede yi, Ọgagun Muhammadu Buhari ninu.. Aarẹ Buhari si ti jẹ ko di mimọ pe Ọnọrebu Gbajabiamila loun yoo fẹ lati ba ṣiṣẹ pọ ninu ijọba saa ẹlẹẹkeji yi.

"Gẹgẹ bi alaga awọn to ṣẹṣẹ de ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti mọ jẹ, emi ni mo wa nipo lati sọ ọ sita pe bi a ṣe yan Ọnọrebu Gbajabiamila ko ni itako tabi ikunsinu kankan ninu rara, to si jẹ pe tọka-tọkan ati ifẹ pẹlu idunnu la fi gba a wọle kaakiri gbogbo awọn ẹgbẹ oselu lati jẹ olori wa. mo si tun sọ ọ pẹlu igboya pe gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ni wọn tun fọwọ sii.

"Oṣelu ẹtanu to n lọ nipa Ọnọrebu Gbajabiamila  lasiko yi jẹ eyi to bani lọkan jẹ nitori pe irọ ati ibanilorukọ jẹ lasan ni, ti wọn si fẹẹ fi bori otitọ to ti farahan tẹlẹ, ṣugbọn iyẹn ko tu irun kankan lara wa. Sibẹ, gbogbo awọn iroyin alupayida yi to n wa lati ọwọ awọn ọbayejẹ yi la wa fi n da awọn eeyan loju pe okun ati agbara lo tubọ n fun awa ti a wa lẹyin Ọnọrebu Gbajabiamila ati Ọnọrebu Wase.

"Siwaju si, a tun fẹẹ jẹ ko di mimọ pe gbogbo ahesọ to n lọ kaakiri pe bi ẹ ba lọ wo itan Ọnọrebu Gbajabiamila kaakiri, ẹ maa rii daju pe wọn ko tii fẹsun jibiti kan an ri, paapaa nilẹ Amẹrika, Naijiria atawọn ilẹ min in lagbaye. Ko si ajọ tabi ẹgbẹ kan to tii fẹsun jibiti tabi ikowojẹ, tabi jẹgudujẹra kan Ọnọrebu Fẹmi ri, iru aridaju wo la tun n wa nipa awọn ẹsun buruku ti wọn fi n kan ọkunrin to ni iwa mimọ yi?. Ko da ti Amofin ilu Georgia tun gbe oṣuba kare fun un.

"Afojusun Gbajabiamila ati Wase yi naa tun ni ontẹ Gomina Nasir Ẹl-Rufai ninu, to si tun sọ pe yoo ṣe Aarẹ Buhari lanfaani ti wọn ba jọ ṣiṣẹ papọ. Bẹẹ lo tun gbe oṣuba kare fun Aarẹ Buhari bo ṣe bu ọwọ luu."

O wa a rọ gbogbo awọn araalu pe ki wọn ma ṣe gbọ nnkan tawọn abanilorukọ jẹ n sọ nipa ọkunrin naa nitori pe iwa ibajẹ tawọn gan an fẹẹ hu, lo mu ki wọn ma a wa ijakulẹ Ọnọrebu Gbajabiamila tawọn fọwọ sii.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI