ẸGBẸ AKỌROYIN NIPINLẸ OGUN BA ỌGBẸNI KUNLẸ ṢOMỌRIN YỌ LORI IPO TUNTUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, June 9, 2019

ẸGBẸ AKỌROYIN NIPINLẸ OGUN BA ỌGBẸNI KUNLẸ ṢOMỌRIN YỌ LORI IPO TUNTUN

Ẹgbẹ akọroyin nipinlẹ Ogun labẹ alaga wọn Kọmureedi Olusọji Amosu ti fi ẹmi idunnu ẹ han si akọwe agba lori ọrọ iroyin tuntun ti Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọba Dapọ Abiọdun yan laipẹ yi, iyẹn Ọgbẹni Kunle Ṣomọrin.

Ninu atẹjade ti akọwe ẹgb]ẹ naa, Ọgbẹni Ayọkunle Ewuoṣo fi sita, eyi ti ẹda ẹ tẹ AWIKONKO lọwọ lo ti jẹ ko ye wa pe inu ẹgbẹ naa dun gidigidi lori igbesẹ ti Gomina Abiọdun gbe lati yan ọkan lara wọn sipo agba nipinlẹ naa, to si tun jẹ ko di mimọ pe ọna ti ko ni kọnun-kọhọ ninu lo gba yan an.


O ni ọna lati jẹ ki ibaṣepọ to dan mọnran wa laarin ijọba tuntun yi ati ẹgbẹ akọroyin ni Gomina Abiọdun mu wa si imuṣẹ, paapaa lati gbe ipinlẹ naa ati orilẹ-ede Naijiria ga.

Bẹẹ lo tun sọ pe ko jẹ iyalẹnu fun ẹgbẹ akọroyin lori bi wọn ṣe yan ọkunrin naa, nitori pe wọn ti ri ipa ati iṣẹ takuntakun to ti ṣe ninu iroyin.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI