GBOGBO ILEEWE ẸKỌṢẸ PATAPATA LA FẸẸ MU IDAGBASOKE BA - IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, June 16, 2019

GBOGBO ILEEWE ẸKỌṢẸ PATAPATA LA FẸẸ MU IDAGBASOKE BA - IGBAKEJI GOMINA IPINLẸ OGUN

Gbenga Ọladipupọ

Igbakeji gomina ipinlẹ Ogun, Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele ti fọwọ sọya pe gbogbo awọn ileewe ẹkọṣẹ (vocational and technical) patapatapa to wa nipinlẹ Ogun ni agbekalẹ ti wa fun un lati mu idagbasoke alailẹgbẹ ba wọn, ko si le duro lati figagbaga pẹluu awọn akẹgbẹ wọn.

Onimọ-ẹrọ  Salakọ-Oyedele lo sọrọ naa lasiko to n gba ẹgbẹ awọn Onimọ-ẹrọ lorilẹ-ede Naijiria, ẹka tipinlẹ Ogun lalejo ninu ofiisi ẹ to wa ni Oke-Mọsan, Abẹokuta, nibẹ lo ti sọ pe ipo tawọn ileewe naa wa ko ba oju mu, bẹẹ ni ko ba ẹkọ igbalode asiko yi mu, to si ni ijọba ti gbe ilana kalẹ, tawọn yoo fi mu ayipada gidi de ba wọn.

Alaga ẹgbẹ awọn Onimọ-ẹrọ lorilẹ-ede Naijiria (Nigerian Society of Engineers (NSE) niluu Abẹokuta, Onimọ-ẹrọ Ọlanrewaju Ahmẹd Apampa to lewaju awọn ikọ ẹ lọọ ṣabẹwo ikinni si igbakeji gomina naa sọ pe gbogbo awọn ileewe ẹkọṣẹ naa patapata lawọn ti lọ, tawọn si awọn iṣoro ati ipenija ti wọn n dojukọ.

O ni gbogbo awọn ileewe naa lo nilo abojuto gidi, nitori pe awọn ileewe naa lo jẹ pe awọn ọgbọn loriṣiriṣi ẹka ti gba ibẹ jade, to si tun fawọn akẹkọọ lati da ara wọn silẹ lai tọrọ jẹ.

Siwaju sii lo sọ pe awọn gbogbo awọn ẹka iṣẹ to wa lawọn ileewe yi lo nilo awọn olukọni ti wọn yoo maa ṣe idanilẹkọọ atigbadegba fawọn akẹkọọ, eyi ti yoo jẹ ki wọn ba ẹkọ igbalode mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI