NITORI JUNE 12 ATI MKO ABIỌLA: Ẹ GBỌ NNKAN TI ALAAFIN ỌYỌ SỌ NIPA BUHARI - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, June 16, 2019

NITORI JUNE 12 ATI MKO ABIỌLA: Ẹ GBỌ NNKAN TI ALAAFIN ỌYỌ SỌ NIPA BUHARI

Ọla Eyitayọ, Ọyọ

Alaafin Ọyọ, Iku Baba Yeye, Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Muhammadu Buhari fun bo ṣe sọ gbogbo ọjọ kejila oṣu kẹfa di ayajọ ọjọ iṣejọba awaarawa, to si tun ṣapejuwe Aarẹ gẹgẹ bi aṣiwaju rere.

Ọba Adeyẹmi to tun jẹ alaga igbimọ awọn Ọba atawọn Oloye nipinlẹ Ọyọ sọ pe oun ko le sọ bi inu oun ṣe dun to fun bo ṣe sọ Oloogbe MKO Abiọla di akọni ti ko ṣe e gbagbe titit latari ipa to ko lorilẹ-ede yi nipa idagbasoke ati ilọsiwaju, ko to o gbe apoti ibo.

Ninu atẹjade kan ti Alaafin Ọyọ fi ki Aarẹ Buhari lo ti ṣapejuwe Oloogbe Abiọla gẹgẹ bi akikanju eniyan, oludasilẹ ile-iṣẹ nla, ontẹwe ati oloṣelu to duro digbi lasiko ipọnju, ti itan ẹ ko si nii parẹ lorilẹ-ede yi, paapaa lagbaye.
 
Bẹẹ lo sọ pe bi wọn ṣe da esi ibo June 12, ọdun 1993 ṣi n ro kii lọkan awọn ọmọ Naijiria, ti wọn ko si le gbagbe nnkan ti wọn padanu, ko da a, lẹyin ọdun mẹrindinlọgbọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI