IJỌBA IPINLẸ OGUN ṢELERI LATI MU IDAGBASOKE BA JUNE 12 - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉThursday, June 13, 2019

IJỌBA IPINLẸ OGUN ṢELERI LATI MU IDAGBASOKE BA JUNE 12

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ manigbagbe lọjọ kejila oṣu kẹfa jẹ lati nnkan bi ọdun mẹrindinlọgbọn ninu itan orilẹ-ede yii ti wọn si maa n ya sọtọ lawọn ipinlẹ kan ṣugbọn tọdun yii yatọ nitori pe wọn ti fi pe ori ijọba tiwa-n-tiwa, eyi ti wọn ṣe kaakiri orilẹ-ede yii, ti wọn si n jẹ kawọn eeyan mọ pe ọjọ naa ko le pare lailai.

Ni papa iṣere MKO Abiọla, to wa ni Kutọ, niluu Abẹokuta, lawọn ọmọ ipinlẹ tu yaya jade wa lati wa si ayajọ ijọba tiwa-n-tiwa naa, nibi ti oriṣiriṣi eto ti waye.

Ninu ọrọ Onimọ-ẹrọ Nọimọt Salakọ-Oyedele, igbakeji gomina ipinlẹ Ogun sọ lorukọ Gomina Dapọ Abiọdun lo ti rọ awọn oloṣelu lati ma ṣe rẹwẹsi tabi fa sẹyin lori nnkan ti June 12 duro le lori nipa ijọba tiwa-n-tiwa tawọn eeyan janfaani ẹ loni in.

O tun gba awọn ọmọ Naijiria nimọran lati lo ifaraji ti MKO Abiọla ni lori ọrọ ijọba tiwa-n-tiwa pese iṣejọba tuntun fun anfaani awọn ọmọ orilẹ-ede yii ko le tẹ siwaju, ko si mu eso rere jade.

Igbakeji gomina tun lo akoko naa lati dupẹ lọwọ awọn ọmọ ipinlẹ Ogun fun igbagbọ ti wọn ni ninu ijọba tuntun yii pẹlu idaniloju pe ijọba Dapọ Abiọdun  ti ṣetan lati pese iṣejọba tuntun lati mu igbe aye rọrun fawọn araalu.

O ni awon ti pinnu lati pese isejoba tuntun lati mu inu awon eeyan dun iru eyi to ni Oloogbe Oloye MKO Abiola ni lokan lati se laifi ti eleyameya si pelu ileri pe erongba awon ni lati mu ki ipinle Ogun goke agba ju bo se wa loo.

Ninu ọrọ ti Ọlakunle Oluọmọ, to jẹ olori ile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, lo ti ṣakiyesi pe ijangbara ọjọ kejila oṣu kẹfa ko gbọdọ lọ lasan, o wa gba gbogbo awọn oloṣelu lati wa ni iṣokan lati fi le gbogun ti oṣi ati ipọnju lorilẹ-ede yii.

Lara awọn to tun sọrọ nibi ayẹyẹ to waye naa ni ọkan lara ọmọ MKO Abiọla, awọn mii in to tun sọrọ ni Sylvester Odiọn,  Wale Ọṣun, Fẹmi Aboriṣade, Arabinrin Funkẹ Fadugba atawọn mii in.

- BOṢERI

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI