Olúwo ti ìlú Iwo Ọba Abdulraṣheed Akanbi ti ké si
àwọn Ọba aládé ní gbogbo ilẹ̀ Káàrọ oò-jííre láti kúrò nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn ti
wọ́n ń ṣe, ati pe alainitiju ni gbogbo wọn lati maa ṣagbatẹru ẹgbẹ okunkun.
Olúwo ni gbogbo àwọn ẹgbẹ́ báwọnyìí máa ń sọ wọ́n di
ẹrú ni nígbá ti wọ́n ba jẹ́jẹ̀ẹ́ owó àtí àwọn agbára ẹmi àìrí.
Gẹ́gẹ́ bó ṣe sọ nínú àtẹjade kan to fi síta láti
ọwọ́ akọwé rẹ̀ Alli Ibraheem, Oba Abdulrasheed ní okiki wọ́n ti dínku nípa àwọn
ẹgbẹ́ ti wọ́n ń ṣe.
O ní ọ̀pọ̀ Ọba ní ìhà ìwọ̀ -òòrun -Guusu ní láti
dári jọ ṣe àgbékalẹ̀ ìgbìmọ ti yóò dá ògo Yorùba àti àṣẹ ti Ọlọrun fún wọ́n
pada gẹgẹ bii Ọba.
Ọba Akanbi ké si Alaafin Oyo, Oba Lamidi àti Awujale
ti Ijebu Oba Sikiru láti sááju ìjàgbara kúrò lọ́wọ́ ẹgbẹ́ okunkun.
O ní " Àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn ti gbá gbogbo ẹtọ
Ọba. Ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà ní pe kí àwọn asáájú ọba jìjàgbara. Mo ri
Alaafin àti Awùjalẹ̀ gẹ́gẹ àwọn tí wọ́n ni ìgboyà. Baba Alaafin lé sááju
ìpolongo pẹ̀lú Awujale, wọn mọ ìtàn."
- BBC
No comments:
Post a Comment