Guro Reiten ti ikọ Norway lo kọkọ gba bọọlu naa si
inu awọn ni isẹju mẹtadinlogun ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ, ko to di wi pe
Lisa-Marie Utland naa fi ọba le, to fi jẹ ami ayo meji si odo.
Osinachi Ohale ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria naa lo wa
bọrọ jẹ patapata, ti o si gba bọọlu wọle si oju ile ara rẹ, eyi to mu ki ifẹsẹwọnsẹ
naa pari si aami ayo mẹta si odo fun ikọ Norway.
Ikọ agbabọọlu Norway to gba Ife Ẹyẹ naa ni ọdun 1995
lo jawe olubori pẹlu bi ko se si gbajugbaja elere bọọlu wọn, Ada Hegerberg ni
ifẹsẹwọnsẹ naa.
BBC
No comments:
Post a Comment