JUNE 12: YORUBA FẸẸ GBAJỌBA KURO LỌWỌ AWỌN FULANI DARANDARAN NI TIPATIPA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉSunday, June 9, 2019

JUNE 12: YORUBA FẸẸ GBAJỌBA KURO LỌWỌ AWỌN FULANI DARANDARAN NI TIPATIPA

Ọlaide Ọṣinuga, Eko 

Lati dẹkun wahala ti wọn lawọn Fulani daran-daran ko wọ ilẹ Yoruba kaakiri, gbogbo awọn ẹgbẹ to n jijagbara fun ilẹ Yoruba kaakiri lawọn ti ṣetan lati gba ijọba ilẹ wọn pada nipa didẹkun awọn wahala awọn Fulani naa.

Lati bi i ọdun meloo kan sẹyin, paapaa latigba ti Aarẹ Buhari ti gbajọba lawọn Fulani darandaran ti n fogun ja awọn eeyan nilẹ Yoruba, to si tun jẹ pe ọna ti wọn n gba ṣe ijamba bayii ni ijinigbe, pipa awọn agbẹ, fifi maluu jẹ oko awọn agbẹ, atawọn oriṣiriṣi iwa min in ti ko yẹ ọmọluabi lawujọ, gẹgẹ ba a ṣe gbọ.

Eyi ni wọn sọ pe ijọba apapọ ko wa nnkan ṣe sii lẹyin ọpọlọpọ ariwo.

Lara awọn ẹgbẹ ta a gbọ pe wọn ko ara wọn jọ lati gba ilẹ Yoruba silẹ kuro lọwọ awọn Fulani yi ni: Voice Of Reason (VOR), Committee for the Defense of Human Rights (CDHR), KAARỌ OJIIRE ỌMỌ OODUA FOUNDATION, Nigerian Women For Progress in Politics, Yoruba Council Of Youth Worldwide, Oduduwa United People's Association ati Vigilante Group Of Nigeria.

Awọn min in tun ni: Oodua Youth Coalition, Oodua National Congress, Yoruba Hunters Association, Oodua Coalition Against Insurgency and Kidnapping in Yoruba Land, Coastal Liberation Movement, Yoruba Survival Group, Movement for Oduduwa Republic, Oodua National Coalition, FYCC, Agbekoya Fraternity Movement atawọn min in.

Ni bayii, a gbọ pe gbogbo eto lo ti pari nigba ti gbogbo awọn ẹgbẹ yi kora wọn jọ sabẹ Yoruba Kọya Leadership & Training Foundation lati bẹrẹ iwọde ifẹhonu han naa kaakiri gbogbo ilu to wa lawọn ipinlẹ Yoruba kaakiri.

Akori iwọde naa ni wọn pe ni "SAFETY AND SECURITY IN YORUBA LAND", ti yoo si bẹrẹ lati aago mẹsan an aarọ pẹlu aṣọ funfun.

EYI LAWỌN ILU ATI AGBEGBE TI IWỌDE NAA YOO TI BẸRẸ ATAWỌN ALAKOSO

EKOO: Gani Faweyinmi Freedom Park, Ojota
Central Coordinators:
Arc. George Akinola: 08034253639 ati
Barr.  Dotun Hassan: 08033931229.

ỌYỌ: Ibadan Military Cenotaph  to wa ladojukọ ilegbe ijọba, Agodi.
Central Coordinator:
Dr. Tunde Hamzat: 08073561915

OGUN: Ikorita Panṣẹkẹ, Abẹokuta
Central Coordinators:
Ọgbẹni Biọdun Ọṣifẹsọ: 08036759719
Ọgbẹni Timothy Ọdẹdina: 08037161592 ati
Ọgbẹni Paul Oni: 08033488703

EKITI: Ikorita Fajuyi, Ado-Ekiti
Central Coordinators:
Oloye Jimoh Aliu: 08034525224 ati
Ọgbẹni Fẹmi Alongẹ: 08060265794

ỌṢUN: Nelson Mandela Freedom Park, Osogbo
Central Coordinator:
Adekanọla Desmond: 08052537616, 08033626318

ONDO: Ikorita Alagbaka ladojukọ First Bank, Akure.
Central Coordinator:
Oluyi Akintade Tayọ Alariwo: 08034562871

KOGI: Adojukọ Aafin Ọbarọ, Kabba.
Central Coordinator:
James Ọbasa: 07089660025, 08035063229

KWARA: Opopona Ibrahim Taiwo, Ilorin:

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI