ILẸ-IṢẸ FOOMU N JỌNA LỌWỌ L'ỌṢUN O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, June 14, 2019

ILẸ-IṢẸ FOOMU N JỌNA LỌWỌ L'ỌṢUN O

Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun
 
Ọrọ di boolọ-o yago lọna laarọ onii nigba ti ile-iṣẹ foomu nla kan ti wọn pe ni Yinka Ọba Foam Company deede gba ina lojiji, to si ti fẹẹ ba ọpọlọpọ dukia to wa nibẹ jẹ.

Bo tilẹ jẹ pe a ko tii gbọ nipa nnkan to ṣokunfa bi ile-iṣẹ na ṣe gbana, ṣugbọn a gbọ pe awọn oṣiṣẹ ile-iṣẹ pana-pana ti wa nibẹ titi dasiko ta a kọ iroyin yi tan, tawọn oṣiṣẹ eleto aabo naa si ti wa nibẹ.

Ni nnkan bi aago mejila ku iṣẹju diẹ la gbọ pe awọn oṣiṣẹ naa ri ina lo n ṣẹyọ, sugbọn ti ko tete ka a sii, ṣugbọn nigba to se dee de dun gbua, lo mu kawọn eeyan bẹrẹ sii wa ọna lati sa jade, sa asala fun ẹmi ara wọn.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI