NITORI ETO AABO, GOMINA OYETỌLA SARE LỌỌ ṢEPADE PẸLUU BURATAI L'ABUJA, BO ṢE N DỌBALẸ, LO N RABABA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉFriday, June 14, 2019

NITORI ETO AABO, GOMINA OYETỌLA SARE LỌỌ ṢEPADE PẸLUU BURATAI L'ABUJA, BO ṢE N DỌBALẸ, LO N RABABA


Folukẹ Aduragbemi, Ọṣun

Beeyan ba wa nibi ti Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Adegboyega Oyetọla ṣe n rababa, dọbalẹ bẹ olori ologun orilẹ-ede Naijiria, yoo mọ pe ọrọ naa kii ṣe oju lasan mọ, o ti kọja oju tawọn eeyan fi n wo o.

Kii ṣe ahesọ pe eto aabo ilẹ Yoruba ti mẹhẹ kọja afẹnusọ lasiko ti a wa yii, ṣugbọn ọna ti aisi eto aabo to peye n gba lasiko yi ti kọja oju tawọn araalu, paapaa awọn ilẹ Yoruba fi n wo o.

Idi ni yii ti Gomina ipinlẹ Ọṣun, Alaaji Adegboyega Oyetọla ṣe sare gba ilu Abuja lọ, lọdọ ọga agba patapata lẹka eto aabo ologun, to si n lọ n dabalẹ bẹbẹ pe ko ma ṣe laju silẹ, ki ipinlẹ naa bajẹ mọ oun lori, ko si tẹtẹ wa nnkan ṣe lati dekun wahala to n ṣẹlẹ nibẹ.

Ninu atẹjade ti akọwe iroyin Gomina ipinlẹ naa,Ọgbẹni Adeniyi Adeṣina fi sita lo ti jẹ ko di mimọ pe ẹbẹ ni Gomina Oyetọla lọ n bẹ niluu Abuja nigba to lọọ ba olori awọn ologun naa.

Bẹ o ba gbagbe, laipẹ yi ni ijọba ipinlẹ Ọṣun gbe igbimọ eleto aabo kan dide, nibi tawọn eleto aabo patapata ti tọwọ bọwe adehun lati ṣiṣẹ papọ gbogun ti iwa ọdaran bii ijinigbe, ipaniyan atawọn min in to n ṣẹlẹ lawọn oju popona kaakiri ipinlẹ naa, iyẹn loru ọganjọ.

Lẹyin agbekalẹ igbimọ naa ni ijọba kọ lẹta si ọga ologun naa lati ba wọn fi ontẹ luu pe awọn ologun, ọlọpaa, sifu difẹnsi atawọn eleto aabo yooku ti panupọ lati fọwọsowọpọ, ki iṣẹ si le tete bẹrẹ ni pẹrẹu, idi ni yi to fi lọ nigba ti ko tete gbọ esi lẹta naa.
 
Gomina Oyetọla lo tun jẹ ko di mimọ pe apapọ awọn Gomina ilẹ Yoruba ti forikori lati gbe igbimọ eleto nla dide, iyẹn nibi eto nla kan to nii ṣe pẹlu eto aabo nilẹ Yoruba jakejado ti yoo waye laipẹ yii.

No comments:

Post a CommentPÍN-IN KÁÀKIRI