ILẸ̀ N YỌ̀ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, June 18, 2019

ILẸ̀ N YỌ̀


Láti ọwọ ọ - JLÁADÉ ADÉLAKÙN


Ilé n yò.

Olówó ayé o se mèdò.

Mèkúnù ayé sóra re.

Kòlòkòlò kan nilé ayé tí n gbéni mì lááyè.

Báyé bán lo, won a ní ó n yí bí aago.

Báyé bá n sáré títí, n padè bòwá.

Sé owó loní tí gànran- gànràn ré wà pò.

Sé ipò gíga lo wà, tí o wá n sapá yanga-yanga.

Òpó gbonranran tí o wà lókè re yii, rántí pé èèyàn lo fi s'àtègùn e.

A kìí súré títí ká kojá ilé.

A kìí rìn gbèrè ká sùn lébá ònà.

Ohun a fèsò mú kìí bàjé, ohun a f'agbára mú, kokoko báyíi ní n le!

B'áyé bá ye ó, má se dunnú jù.

Torí olówó ànà kúrò l'éni a n fò kúrò l'éyìnkùlé fún.
 
Òpò alàgbára lóti subú.

Òpò akínkanjú lóti wolè lááyè.

Ilè n yò.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI