IPO ỌBA DA WAHALA NLA SILẸ NILUU ỌLAPELEKE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 19, 2019

IPO ỌBA DA WAHALA NLA SILẸ NILUU ỌLAPELEKE

Akanbi Olowosusi

Bi ẹ ṣe n ka iroyin yi, ara ko tii rokun, bẹẹ ni ara ko tii ro adiyẹ niluu Ọlapeleke ni Itori, ijọba ibilẹ Ewekoro nipinlẹ Ogun lori bi wọn ṣe sọ pe ipo ọba lo da wahala nla silẹ, ti wọn si ti bẹrẹ sii fi oogun le ara wọn kaakiri bayii.

Ọsẹ to kọja yi niroyin naa tẹ AWIKONKO lọwọ nigba ti wọn sọ pe ọkunrin kan ti wọn pe orukọ ẹ ni Adebari Ọdẹkunle Thomas ṣa dede gbe ade wọlu pẹluu awọn tọọgi.

Oloye Gabriel ati Olowu tiluu Owu

Wọn ni bawọn tọọgi naa ṣe ya wọlu ni wọn ti bẹrẹ sii lu awọn eeyan ti wọn ko gba ti wọn, ati pe kii ṣe pe wahala naa dede bẹ silẹ, bi ko ṣe ohun ti wọn sọ pe gomina ana nipinlẹ naa, Ibikunle Amosun ṣe fawọn eeyan ti ko din ni marundinlọgọrin (75) jẹ ọba, ti wọn si ni pupọ ninu wọn ni ko tọ si ipo ọba.

A gbọ pe ọdun 2009 ni Olowu tiluu Owu, Ọba Adegboyega Dosumu ati Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ fi Oloye Gabriel Taiwo Oluṣṣsan Akinrẹmi jẹ oye Baalẹ ilu Ọlapeleke.

Oloye Adebari ti wọn loo gbe ade wọluu
Latigba naa la gbọ pe wọn ti n kọ lẹta lati gba ọba niluu naa gẹgẹ bi Olu-iluu Ọlapeleke, ti wọn si ni ijọba ipinlẹ Ogun fi ontẹ luu pe awọn ti gba lẹta wọn, ati pe igbesẹ yoo bẹrẹ lori ẹ.

A gbọ pe ija to wa laarin Oloye Gabriel Akinrẹmi ati Ọba Akamọ ni ko jẹ ki Ọba Akamọ fọwọ si bi wọn ṣe yan Oloye Gabriel, ta a si tun gbọ pe ọrọ naa da yanpọnyanrin silẹ laarin ilu.

Ṣadede lọsẹ to lọ lọhun tii ṣe Fraide ni wọn sọ pe Oloye Thomas atawọn tọọgi ẹ gbe ade wọlu, lai ṣe pe ẹnikẹni gbe ade naa le e lori, tabi fi jẹ ọba, awọn ti wọn sọ pe wọn n beere ibi to ti ri ade la gbọ pe awọn tọọgi naa kọju ija sii, ti wọn si bẹrẹ sii lu awọn eeyan lalubami.

Oloye Gabriel Aderẹmi sọ pe oun ni baalẹ to lẹtọọ lati di Olu-Ọlapeleke labẹ ofin, to sọ pe iwa ti gomina ana hu ku diẹ kaato lati maa fi awọn oloṣelu jọba le awọn araalu lori.

Nigba to n tako ẹsun ti wọn fi kan an, Oloye Adebari Ọdekunle Thomas to loun ni Ọtun Baalẹ ilu naa tẹlẹ sọ pe Olowu tiluu Owu lo gbe ade naa foun lẹyin ti gomina ana, Ibikunle Amosun ti kede orukọ oun gẹgẹ bi ọba.

O wa lawọn ọta oun ni wọn wa nidi madaru tori pe oun nijọba ipinlẹ Ogun labẹ Gomina Amosun fa kalẹ gẹgẹ bi ọba, ti ko si sẹni to le di oun lọwọ lati ma de ipo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI